Yoruba

Egbe Agbaboolu Wikky Tourist Padamu Oko Akero Won Sinu Isele Ijamba Oko

Nise ni oko-akero tegbe agbaboolu Wikky Tourist jona furu-gurru, ninu ijamba oko to waye lopopona Kibboo, nilu Jos nipinle Platu.

Egbe agbaboolu ohun to fi ilu Bauchi se ibujoko, lowa loju ona re silu Wuyo, nipinle AkwaIbom, fun ifesewonse pelu egbe agbaboolu Dakkada.

Gege bi iroyin se wii, ebge agbaboolu oohun lokuro ni ibugbe won lowuro kutu-kutu oni, ki ise labi naa to sele nilu Jos.

Ewe, emikan ko ba isele naa rin, yato fun pe, awon omo-egbe agbaaboolu naa atawon alakoso won padanu dukia won.

Ogunyemi/Idogbe 

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *