Yoruba

Àjọ tón rí sétò ìkànìyàn gbé ìgbésẹ̀ sáàjú ètò ìkànìyàn ọdún 2021

Àjọ tó ń rí sétò ìkànìyàn nílẹ̀ yíì ti gùnlé ètò ìlanilọ́yẹ̀ fáwọn èèyàn tó wà lẹ́kùn ìjọba ìbílẹ̀ gúsù Ogbomọshọ àti Surulere nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, lórí ètò ìkànìyàn fún tọdún 2021, láwọn agbègbè tó wà lẹ́nu àlaà[.

Ẹnìkan tétò náà sojú ẹ̀, láwọn ìjọba ìbílẹ̀ méjèejì, ọ̀gbẹ́ni Adedayẹ Adelọwọ, sọ pé ètò ìkànìyàn tí yóò wáyé láwọn agbègbè ẹnu áàla náà, ló wà sáàjú èyí tí yóò wáyé nílẹ̀ yíì, lápapọ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò náà, alákoso fétò ìkànìyàn tójẹ́ tìjọba àpapọ̀ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀mọ̀wé Eyitayọ Oyetunji sọpé, pàtàkì ètè náà ni láti làwọn arálu lọ́yẹ̀ lórí pàtàkì ètò ìkànìyàn ọ̀hún.

Alákoso náà wá gbàwọn olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ méjèèjì nímọ̀ràn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òsìsẹ́ olùkànìyàn tíwọ́n gbé kalẹ̀ nílẹ̀ Nìajírìa.

Kò sài fikun pé ètò náà tó sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni láti fi ìmọye àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan tó wà nílègbé kọ́ọ̀kan.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, ọmọ ilé tón sojú ẹkùn ìdìbò ìjọba àpapọ̀ Ògo Oluwa, Surulere, ọ̀gbẹ́ni Sẹgun Odẹbunmi gbórínyìnfáàrẹ Muhammadu Buhari fágbekalẹ̀ ètò náà, pẹ̀lú àlàyé pé, ètò náà yóò sèrànlọ́wọ́ fún ìjọba láti mọ bí yóò se mọ́rọ̀ ìgbáyégbádùn àwọn èèyàn lọ́kunkúndùn.

Nígbà tó n fèsì, Ọba alayé tẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ gúsù Ogbomọshọ ònpetu tilẹ̀ ìjẹ́rù Ọba Sunday Oyediran rọ àjọ tó ńrísí ètò ìkànìyàn láti se dédé àgbègbè tó wà lẹ́nu àlàà ọ̀hún.

Aminat/Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *