Yoruba

Awọn asòfin pèfún ìpèsè ẹ̀rọ ítani lólobó fún ìjàmbá iná

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin kejì ti rọ ilé-isẹ́ panápaná ìjọba àpapọ̀ látiridájú pé, wọ́n pèsè àwọn ẹ̀rọ tí yóò máà ta àwọn aráàlu lólobó tísẹ̀lẹ̀ ìjàmbà iná bá fẹ́ wáyé yíká àwọn ọjà tónbẹ lórílẹ̀dè yíì, láti dábobo ẹ̀mí àti dúkia aráàlu àti láti dènà ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbà iná lemọ́lemọ́ nílẹ̀ Nàijírìa.

ọ̀rọ̀ yíì niwọ́n fẹnikò lé lórí lẹ́yìn tí wọ́n jíròrò lórí dídènà ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná nílẹ̀ Nàijírìa, èyí tí ọ̀gbẹ́ni Henry Nwawuba gbékawájú ilé.

Ó sàlàyé pé ọ̀rọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná ti wa ńdi lemọ́lemọ́ nílẹ̀ Nàijírìa, ìdí sinni yí tó fi sepàtàkì láti pinwọ́ rl, fi dabobo ẹ̀mí àti dúkia aráàlu, ọ̀gbẹ́ni Nwawuba kò sài fikun pé, àwọn ọ̀rọ̀ náà tó bá wa láwọn ojú táyé, yóò jẹ́ kó rọrùn fáwọn èèyàn tó bá nibi ìsẹ̀lẹ̀ náà tètè kópa rẹ̀ káwọn òsìsẹ́ panápaná tó dé.

Aminat/Wojuade   

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *