News Yoruba

Àjọ NITDA sèkìlọ̀ lórí ìdúnkokò tuntun orí ẹ̀rọ ayélujára.

Àjọ tó ńrísí ọ̀rọ̀, ìdàgbàsókè ìmọ̀ ẹ̀rọ nílẹ̀ yí NITDA ti kìlọ̀ lórí ìdúnkokò tuntun lórí ẹ̀rọ ayélujára tó ńlọ́wọ́ ìfìwéránsẹ́ lọ́nà ìgbàlódé email, nínú láti ọwọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Russia kan tí wọ́n ńpè ní NOBELIUM.

Ìkìlọ̀ yí ló wá nínú àtẹ̀jáde ti ẹniti ó ńrísí ọ̀rọ̀ tó kàn ará ìlú nínú àjọ NITDA, arábìnrin Hadika Umar fi síta.

Arábìnrin Umar tọ́ka síì wípé ilé isẹ́ Microsoft ti kìlọ̀ lórí ìdúnkokò orí ẹ̀rọ ayélujára tuntun yi ẹnití ti ó ní ó àwọn ọmọ ilẹ̀ Russia náà fojú rẹ̀ kọ ilé Amẹrica àti àwọn àjọ ilẹ̀ òkèèrè miran.

Ó ní àwọn àsùwọ̀n ìfìwèránsẹ́ email tótó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta níya tí àwọn àjọ áàdájọ́ ni páàjùlọ táwọn àjọ tó ńrísí ìlọsíwájú ilẹ̀ òkèrè, ìgbáyégbádùn àti tẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni wọ́n ńdunkokò mọ.

Dada/Net  

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *