News Yoruba

Adari Ile Asofin Ipinle Oyo Tenumo Ipese Aabo Faraalu

Adari ile igbimo Asofin Ipinle Oyo, Ogbeni Adebo Ogundoyin ti se ipade eto aabo pelu awon agbagba atawon olori iko alaabo to fi mo gbogbo awon toro kan nile ibarapa.

Ipade yi ko seyin akolu to waye lojo abameta nilu Igangan, nipa bi awon agbebon se kolu agbegbe naa leyi to ran awon eeyan ti ko din ni ogun sorun apapandodo pelu biba opo dukia je, Ogbeni Ogundoyin salaye wipe, ipade naa to waye nilu Ayete, nijoba Ibile Ariwa Ibarapa lo de le agbeyewo bi inkan se lo pelu iwadi lori ohun to se okunfa akolu naa, nidi ati le je kawon agbofinro duro deede lati koju akolu miinn to ba le fee waye.

Adari ile asofin naa wa rawo ebe sawon agbofinro pe ki won tu gbogbo igbo nla to wa lagbegbe naa yebe-yebe, ki won si se awari ibi ti awon odaran ba n fi ara sinko si lagbegbe naa, ki won le fi kele ofin gbe awon amookun sika eda naa.

Oga agba ilese Olopa agbegbe Ibarapa, Ogbeni Ojo Emmanuel wa so asodaju pe won ti ko awon iko Olopa de ilu Igangan ati agbegbe re fun ipese aabo to peye, bee lo kesi awon olugbe agbegbe naa pe ki won maa se atileyin fawon agboofinro fun ipese aabo to peye.

Okareh/Babatunde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *