Àjọ tó n se kòkárí ọ̀rọ̀ nípa kòkòrò àjàkálẹ̀ àrùn AIDs nílẹ̀ yí NACA, ti se ìfilọ́lẹ̀ ètò ìkówójọ lábẹ́lé fún ìdúrósinsin àjọ náà, láti ọdún 2021 sí ọdún 2025, lọ́nà ti orílẹ̀dè yi yóò fi bọ́ lọ́wọ́ gbígbé ara lé àrùn onígbọ̀wọ́ ilẹ̀ òkèèrè fún ètò ìsúná àjọ náà pẹ̀lú àfojúsùn wọn ọdún 2030.

Níbi ètò ìfilọ́lẹ̀ náà tó wáyé nílu Abuja, olùdarí àgbà àjọ NACA, nílẹ̀ yíì Díkítà Aliyu Gambo sàlàyé ní pé àfojúsùn àjọ náà ni láti le máà se àyẹ̀wò fún ó kéré tán ìdá márùndínlọ́gọ̀rún àwọn tó bá ko si pánpẹ́ àrùn náà, pẹ̀lú ìrírí dájú pé ìlera ń wà fún wọn nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2030.

Alága ìgbìmọ̀ tẹ́ẹ̀kótó ilé asòfin kejì ilẹ̀ yí tó wá fún àwọn àrùn bíì AIDS, ikọfee, àti àisàn ibà, ọ̀gbẹ́ni Abubakar Dahiru rọ àwọn Gómìnà pé kí àwọn náà se ojúse wọn nídi àti fòpin sí àjàkẹ́lẹ̀ àrùn lórílẹ̀èdè yí.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *