Yoruba

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ńsèwádi lórí títẹ̀lé òfin àti ìlànà tó rọ̀ mọ́ àbò lórí on tẹ́nu ńjẹ.

Ile ìgbìmọ̀ asòfin ti pa dandan fúnìgbìmọ̀ rẹ̀ tó n sà kóso ètò ìlera láti sèwádi lórí báwọn èyàn se ń tẹ̀lé òfin tó rọ̀ mọ́ àbò tó péye òn tẹ́nujẹ tẹ̀lé àbò lórí óunjẹ tó fimọ́ àwọn èyí tí wọ́n ń ra wọlé láti òkè òkun.

Ìgbésẹ̀ yí ló wáyé lẹ́yìn tí ilé ìgbìmọ̀ asòfin fẹnukò le lórí.

Ẹni tó gbọrọ̀ ọ̀hún léde, ọ̀gbẹ́ni Adewumi Onanuga fi àidùnú rẹ̀ hàn lórí bí àwọn ilésẹ́ tón sàkóso ipeniye óunjẹ, sen fi ọwọ́ hẹ̀hẹhẹ mú títẹ̀lé òfin tó rọ̀ mọ́ ìpeníye on èlò tí wọ́n ńta nílẹ̀ yí, tí kò sí ní ní àwọn ọ̀rọ̀ tí yo sànfání fáwọn oníbarà, bi àsìkò tí kò ní dara mọ́ fún jíjẹ́ àti bẹbẹlọ.

Asòfin ọ̀hún wá tẹnumọ pé ó se pàtàkì pé kí ìgbẹ́sẹ̀ kọ́mọ́kía jẹ́ gbígbé láti mú kí òpin dé bá sísọ ilẹ̀ Nàijírìa di ibi tí wọ́n yo ma kó àwọn óunjẹ tọ́jọ́ ti lọ lórí rẹ̀, tàbí tí kò ní ìwílò fún ìlera ẹ̀dá, wọ láti òkè òkun.

Àwọn àjọ tọ́rọ̀ ọ̀hún kàn gbọ̀ngbọ̀n náà n i, àjọ èyí tón rísí ipenuye ounjẹ àti ògùn lílò nílẹ̀ yí NAFDAC, ilésẹ́ asọ́bọdè, ilésẹ́ èyí tón dábobo oníbarà nílẹ̀ yí, iyun Federal Competition ànd Consumer protection Commission tófimọ́ àjọ tón mójútó ìpèníjà on èlò nílẹ̀ yí SON.

Ololade Afonja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *