Igbìmọ̀ atọpinpin elétò ìdájọ́ se se aráàlu  nisekuse àtàwọn ìsẹ̀lẹ̀ miin tó fara pẹ́ tí dába owó tó tó billiọnu mọ́kànlélógún naira fún sisan owó gbà mábinú fáwọn tí ọlọ́pa bá gbẹ̀mí wọn lọ́nà àitọ́ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ agbófinró mii.

Alága ìgbìmọ̀ náà, adájọ́ fẹ̀yìntì Young Ogola ló fojú ọ̀rọ̀ yí léde lásìkò tó ń jábọ̀ isẹ́ ìrújú ìgbìmọ̀ rẹ̀ fún Gómìnà Doye Diri nílu Yenogoa.

Adájọ́ fẹ̀yìntì Ogola sàlàyé wípé, ìwé ẹ̀sùn bíì àadọ́ta ni ìgbìmọ̀ náà rí gbà, tí wọ́n sì jábọ̀ níbamu pẹ̀lú ìwádi tí wọ́n se.

Nígbà tó ń gbé àbọ̀ ìgbìmọ̀ náà, Gómìnà Diri dúpẹ́ lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ náà wípé bí wọ́n se se isẹ́ náà tọkàn tara, ó wá jẹ́jẹ àti gbé ìgbìmọ̀ tí yóò rí sí àmúsẹ àbá náà dìde láifi àkókò sòfò.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *