Ilé asòfin ìpínlẹ̀ Ògùn ti sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé, àtúnse òfin ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n ń lò lọ́wọ́ nípinlẹ̀ náà yóò se ìrànwọ́ lórí ìmúpadàbọ̀sípò ìlànà ìsèjọba ìbílẹ̀ nípinlẹ̀ náà.

Èyí ni wọ́n sọ pé yóò mọriiri àwọn òsìsẹ́ ìjọba tí yo si mú igbayegbadun wọn lọkunkundun.

Adarí ilé asòfin ìpínlẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Ọlatunde Oluomọ ló fojú ọ̀rọ̀ yí léde lásìkò ìpàdé àwọn tọ́rọ̀ náà gberu nídi àtúntò òfin ìjọba ìbílẹ̀ nípnlẹ̀ Ògùn tọdún 2006 ìpàdé ọ̀hún ló wáyé ní gbọngan ilé asòfin nílu Abẹokuta.

Ọgbẹni Oluomo sàlàyé wí pé ilé asòfin ìpínlẹ̀ náà ló se odayansi ipo fún àwọn olórí ètò àkóso ìjọba ìbílẹ̀ pẹ̀lú ìlànà owó osù tó gbéwọ̀n níbamu pẹ̀lú owó osù àwọn lógalọga ileesẹ ìjọba àti lajọlajọ.

Ó tẹnumọ wí pé, pàtàkì ìgbésẹ̀ náà ni láti mú ìwúrí bá àwọn òsìsẹ́ ìjọba ìbílẹ̀, kí wọ́n le túnbọ̀ máà fi ara wọn jìn fún isẹ́ ìlú láwọn àgbègbè ẹsẹ̀ kùkú.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *