Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ti gùnlé ìlanilọ́yẹ̀ lórí àyẹ̀wò láwọn ìjọba ìbílẹ̀ márun tí àrùn covid-19 ti nwopo pẹ̀lú àmọ̀nràn fáwọn olùgbé ibẹ̀ láti ríì dájú wípé wọn tẹ̀lé ìlànà ìlera lọ́nà àti dáàbòbò ara wọn lórí ẹ̀yà TUNTUN ÀRÙN COVID-19 tí a mọ̀ si Delta.

Alákoso fọ́rọ̀ ìlera nípinlẹ̀ Ògùn, Dókítà Tomi Coker ló sọ̀rọ̀ yí nílu Abẹokuta.

Alákoso náà rọ àwọn olùgbé ibẹ̀ láti máà tẹ̀lé àwọn ìlànà bíì títakété síra ẹni, fífọ ọwọ́ lóòrekóòre, àti lilo ibomu bomu lọ́nà tótó láti dènà kíkó àrùn ọ̀hún.

Dókítà Coker tún késí àwọn asáàjú àwújọ àti àwọn asáàjú ẹ̀sìn, àwọn ilé isẹ́ ìròyìn àti àwọn tọrọkan gbọ̀ngbọ̀n láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn láti léè se kóríyá fún títẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí.

Alákoso náà wá kéde pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ti ńsàkosílẹ̀ àwọn tó ní àrùn covid-19 tó pọ̀ síì pẹ̀lú bí wọ́n ti se ní àwọn mẹ́ẹ̀dógún tí wọ́n sese ní láàrin ọ̀sẹ̀ méjì tó kọjá.

Wale Oluokun/Oluwayẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *