Ibẹ̀rù bojo ìkọlù látọ̀dọ̀ àwọn molọ kólóun kígbe tón sàkóbá fún kárà kátà nílu ọ̀yọ́ láti àná, ló sin tẹ̀síwájú lóòrọ òní.

Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria tón tópinpin ìsẹ̀lẹ̀ yi jábọ̀ pé, àwọn ilé ìfowópamọ́ lágbègbè náà ní àwọn kò ti sí ilẹ̀kùn rẹ̀, láti má da àwọn oníbarà loun lẹ́yìn tí wọ́n sáré ti ilẹ̀kùn wọn.

Lára àwọn tón sisẹ́ nílé ìfowópamọ́ tí wọ́n bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, sọpé ódi ìgbàtí wan bá gbọ ìròyìn pé àbò tó múnádóko wa, ni wọ́n yo tó mọ bóyá isẹ́ yo bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.

Ìsẹ̀lẹ̀ yí lómú kí àtòtò dábọ̀ wa, nídi ẹ̀rọ tón pọ owó,iyun ATM, pẹ̀lú báwọn oníbarà se ń múra ọdún iléyá.

Ọgagba fún ilésẹ́ ọlọ́pa lẹ́kùn ọ̀yọ́ ọ̀gbẹ́ni Kadmiel Madayi sọ pé ni digbí làwọn òsìsẹ́ àwọn wà, tó sì rọ àwọn olùgbé ìlú ọ̀yọ́ láti fitó wọn létí tí wọ́n bá kẹ́fín on tó mú ìfura lọ́wọ́.

Ololade Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *