Síse àmúgbòrò ẹ̀ka iléèsẹ́ ìjọba tó n rí sí ìgbáyégbádùn aráàlu nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ yóò mú àdínkù bá síse ọmọdé nísekúse láwùjọ.

Èyí lèrò àwọn tó kópa lórí ètò focal point lédè gẹ́ẹ̀sì, níléèsẹ́ wa premier F.M.

Àwọn tó kópa lórí ètò náà tẹnumọ pé kíjọba túnbọ̀ pèsè irinsẹ́ fáwọn òsìsẹ́ ẹ̀ka tó n rísí ìgbáyégbádùn aráàlu, kí wọ́n lè máà se isẹ́ wọn bi isẹ́.

Ònkọ̀wé àwọn ọmọdé, ọ̀mọ̀wé Modupẹ Oyetade sàlàyé wí pé tí ìjọba bá ń kojú ẹ̀bi tàbí rògbòdìyàn kan bá ń wáyé, àwọn èwe ló máà ń fìyà jẹ, àti pé kí ẹni tọ́wọ́ ìyà bá wá lára rẹ̀ tètè ké gbàjarè.

Onímọ̀ nípa ìpèníjà ọpọlọ àwọn ọmọdé, Dókítà Yetunde Adeniyi nínú ọ̀rọ̀ tiẹ náà, tẹnumọ pé ọmọdé yóò wu tó bá ńkojú ìfìyàjẹni léè ní àrùn ọpọlọ tàbí kó di oníjàgídíjà.

Àwọn olùkópa náà sàlàyé pé síse ọmọdé nísekúse ló léè dá ọgbẹ́ ayérayé sọ́kàn irú ọmọ bẹ́ẹ̀, lèyí tó yẹ kí àabò tó péye ó wà fún wọn.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *