Àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀yí, INEC, ẹ̀ka tìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sísàfihàn àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn olùdìbò tuntun káàkiri àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀tàlélọ́gbọ̀n tó wà nípinlẹ̀ yí.

Àkọsílẹ̀ olùdìbò tuntun yi ló jẹ́ ti àwọn tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ forúkọ sílẹ̀ nínú ìpele àkọ́kọ́ ìforúkọ sílẹ̀ olùdìbò tọdún 2021 nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Ọga àgbà àjọ INEC, nípinlẹ̀ yí, Ọ̀gbẹ́ni Mutiu Agboke nígbàtí ó ńbá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní àfihàn àwọn orúkọ olùdìbò tuntun yi jẹ́ láti fi léè fi sàwárí àti yọkúrò àwọn tí ó lẹ́tọ àti forúkọ sílẹ̀.

Ọgbẹni Agboke ní lẹ́yìn àfihàn yí èyítí yio wa sópin lọgbọn ọjọ́ osù yí nìrètí wà wípé ìpele kejì ìforúkọsílẹ̀ yio bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrin osù tó ńbọ̀ títí di ogúnjọ́ osù kejìlá ọdún 2021 yi.

Ọga àjọ INEC, ọ̀hún sàlàyé wípé ó lé lẹ́gbẹ̀rún mọ́kàndílọ́gbọ̀n àwọn ènìyàn tí wọ́n forúkọsílẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára àti ojúkojú nípele àkọ́kọ́.

Ọgbẹni Agboke fikun wípé àjọ elétò ìdìbò ti gùnlé ìlanilọ́yẹ̀ láti léè se kóríyá fáwọn tó lẹ́tọ àti forúkọsílẹ̀ láti se bẹ́ẹ̀.

Ó wá rọ àwọn tọ́rọkàn láti tẹ̀síwájú nídi síse ìrànwọ́ fájọ INEC láti léè jẹ́kí àwọn èèyàn forúkọ sílẹ̀ nípele kejì ètò ìforúkọ sílẹ̀.

Ọlaolu Fawọle/Yẹmisi Owoniko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *