News Yoruba

Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Kejì Bèrè Fún Àgbékalẹ̀ Òfin Tí Yóò Dènà Kíkó Àwọn Ǹkan Ìjagun Wọlé

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin kejì ti ńgbé ìgbésẹ̀ láti fòfinde kíkó àwọn ohun ìjagun wọ orílẹ̀dè yíì.

Àbá òfin ọ̀hún tó wọ́n ti kà fún igbákejì niwọ̀n ti fi sọwọ́ sí ìgbìmọ̀ tí tẹkótó ilé fọ̀rọ̀ ìlànà àti àfẹnukò láti gbéyẹ̀wò.

Ìgbìmọ̀ tẹkótó ilé fọrọ ìlànà àtafẹnukò náà sèpàdé èyítí ọ̀mọ̀wé Nicholas Ossai darí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tọ́tọkàn lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kábọ rẹ̀, alága ìgbpimọ̀  shún ọ̀mọ̀wé Ossai, sọ di mímọ̀ pé, ìgbìmọ̀ náà, ti gbé èróngbà òfin tó fẹnukò lélórí kalẹ̀ síwájú pẹ̀lú àkòrí àpérò àjọ ECOWAS, lórí ohun ìjagun.

Ọmọwe Ossai, fikun pé, ìpàdé ọ̀hún wáyé láti lọ jomitoro ọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ àwọn asòfin láti se àgbékalẹ̀ òfin lórí ohun ìjagun.

Alamu/Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *