Àjọ tó n rísí ìdàgbàsókè ìlànà ètò ìwọléwọ̀de nílẹ̀ adúláwọ̀ ti fàmìn ìdánilógú rẹ̀ hàn lórí dídẹ́kun fàyàwọ́ ọmọnìyà nílẹ̀ adúlawọ̀.

Alámojútó àjọ ọ̀hún lẹ́kùn ìwọ̀ orun ilẹ̀ adúláwọ̀, Ọ̀mọ̀wé Mojisọla Sodẹinde ló sọ̀rọ̀ náà nílu Abuja lásìkò fífọwọ́ bọ̀wé ìgbọ́ra ẹniyé tó wàyé láàrin ilẹ̀ Nàijírìa àti ilẹ̀ olómínìra Niger fún wíwagbò dẹ́kun fún fàyàwọ́ ọmọ niyàn lárin orílẹ̀ẹ̀dè mẹ́jèèjì lórí àjọsepọ̀ wọn.

Ọ̀mọ̀wé Sodeinde sọpé ìlànà náà wáyé lára àwọn ètò tájọ ọ̀hún ńse lóri dídẹ́kun fàyàwọ́ ọmọniyan nílẹ̀ Netherlands.

Ẹwẹ, nínú ọ̀rọ̀ ọ̀gá àgbà àjọ tó ń gbógun ti fàyàwọ́ ọmọnìyàn nílẹ̀yí, Ọ̀mọ̀wé Fatima Waziri tó fàmìn ìdánilójú hàn pé ètò ọ̀hún yóò sọ èso rere, wá sèlérí pé àjọ ọ̀hún yóò se gbogbo ǹkan tó tọ́.

Nígbà tón fọwọ́sí ìwé náà lórúkọ àwọn alásẹ ilẹ̀ Niger, Ousmane Mamane sọpé ọgbọ́ àtúndá náà láàrin ilẹ̀ méjèèjì lórí ìgbógun ti fàyàwọ́ ọmọnìyàn ni yóò sàtìlẹyìn fún ìròyìn àti ìrírí lórí àwọn òfin tó rọ̀mọ́ gbígbógun ti ìwọléwọ̀de lọ́nà kò tọ́.

Blessing Ọkareh/Ayodele Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *