Yoruba

Ajo JAMB Ti Pari Gbogbo Eto Lati Daruko Awon Ibudo Idanwo UTME

Ajo to n risi eto idanwo igbaniwole sawon ile-eko giga, JAMB, ti sope,oun ti pari gbogbo eto lori awon ibudo idanwo ni gbaradi feto idanwo UTME todun 2022.

Eyi lo jeyo ninu atejade kan tajo JAMB fisita fawon oniroyin.

Igbimo oludanwo naa ko sen tun soodi mimo pe, eka to ri soro imo ero lajo jamb ti pari gbogbo awon igbese to ye ni gbigbe, lati fi oruko awon ibudo teto idanwo utme naa yoo ti waye sita pelu afikun pe, ipinnu ajo naa ni lati dena gbogbo awon kudie kudie to se ese ko waye fawon akekoo to fe seto iforukosile fun idanwo ohun to baya.

A o ranti pe saaju lajo JAMB ti sope, o se e se ki idaduro ranpe wa lori eto iforukosile fun idanwo utme todun yii, nitori awon nnkan to suyo, eyi lo koja agbara won.

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *