Yoruba

Gomina Makinde Fidi Isele Iku Otunba Alao-Akala Mule

Gomina Makinde fidi isele iku gomina teleri Otunba Adebayo Alao-Akala mule.

Gomina teleri nipinle Oyo, Otunba Adebayo Alao-Akala ti jade laaye looro oni nilu Ogbomosho tise ilu abinibi re.

Eni to so iroyin di mimo foniroyin ile-isewa, amo tiko fe kiwon daruko oun, sapejuwe iku gomina teleri naa gege bi adanu nla.

Otunba Alao-Akala to je eekan-kan ninu egbe oselu apc, lo je gomina ipinle Oyo laarin odun 2007 sodun 2011.

Nigba ton fidi isele iku Otunba Alao-Akala mule, Gomina Ipinle Oyo, Onimoero Seyi Makinde ti ko le soro nibi isin alajumose eyi tawon osise oba nipinle oyo gbekale fodun tuntun yii, kede didake iseju kan fun Gomina ana to doloogbe ohun, ti Gomina Makinde si pari eto isin alajumose ohun sibe, tawon osise naa si pada se nu ise koowa won pelu irewesi okan.

Nigba ton naa fidi isele iku mule, igbakeji oludari feto iroyin fun gomina teleri naa, Tolu Mustapha sope, kii se aiisan lo pa Otunba Alao-Akala.

Eni odun mokanle-laadorin loloogbe Alao-Akala jade laye.

Folakemi Wojuade/Iyabo Adebisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *