Yoruba

Ẹgbẹ́ àwọn tó ńpèsè ǹkan nílẹ̀ Nàijírìa MAN, sọ pé àtúntò tówáyé lẹ́ka ìgbìmọ̀ tó ńrísí ìgbaninímọ̀ràn fétò ọrọ̀-ajé EAC, látọwọ́ àarẹ Buhari jẹ́ èyí tódara gba, lákokò tó yẹ tó sì ńfìdí ìpinu àarẹ fétò ọrọ̀-ajé tó dúró re múlẹ̀.

Nínú àtẹ̀jáde kan tólùdarí àgbà fẹ́gbẹ́ MAN, ọ̀gbẹ́ni Muda Yusuf fisíta ó pèfún àtúnyẹ̀wò kíakía, lórí àwọn ìlànà ìjọba àpapọ̀ fétò ọrọ̀-ajé.

Ó wá dába pé, kájọ EAC, sisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìgbòmọ̀ àpapọ̀ tó ńrísí àfẹnukò ètò ọrọ̀-ajé nílẹ̀ adúláwọ̀.

Kemi Ogunkọla/Lara Ayọade