Lifestyle

Arẹ Buhari Fẹmi Ọpẹ Han fun Atunyansipo

Arẹ Muhammadu Buhari ti fẹmi ọpẹ han si Ọlọrun ati awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria fun anfani ti wọn fun lati fi dari orilẹ ede yii fọdun mẹrin miran.

Arẹ Buhari nigba ton fesi lori aṣeyọri idibo to waye kan sara sawọn oṣiṣẹ agbofinro fun bi wọn ṣe pese aabo to peye fun ikesejari idibo naa to si ṣeleri lati mọle ori aṣeyọri rẹ ati ọdun mẹrin seyin.

Alaga ajọ eleto idibo apapọ nilẹ yii, ọjọgbọn Mahmood Yakubu sọ pe arẹ Buhari lo ni ibo million 15, ẹgbẹrun lọna igba ati ojilelegbẹrun o le meje (15,191,847) lati fi fẹyin alatako rẹ pẹkipẹki Alhaji Atiku Abubakar tẹgbẹ oṣelu PDP atawọn olujide yoku janlẹ lawọn ipinlẹ 19.

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *