Yoruba

Ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ìpínlẹ̀ Ọyọ sọ ísepàtàkì owó osù tuntun

Ẹgbẹ́ òsìsẹ́ nílẹ̀ yíì, NLC, ẹ̀ka tìpínlẹ̀ Ọyọ, ti tẹnumọ́ ìdí tó fi sepàtàkì fúnjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ láti jígìrì sọ́rọ̀ ìpèníjà sísan owó osù tuntun fáwọn òsìsẹ́ tó kéré jùlọ nípinlẹ̀ yíì.

Alága ẹgbẹ́ NLC, nípinlẹ̀ Ọyọ, ọ̀gbẹ́ni Titilọla Sodo ló fìdí ọ̀rọ̀ yíì múlẹ̀ lẹ́yìn ìpàdè tíwọ́n se pẹ̀lú Gómìnà Seyi Mikinde.

Ọgbẹni Sodo sàlàyé pé, àbẹ̀wò ẹgbẹ́ náà sepàtàkì láti dìjọ fi sàmúlò owó osù tuntun tó jẹ́ tàwọn òsìsẹ́ tó kéré jùlọ náà, tíwọ́n yóò sì fẹsẹ̀ àjọsepọ̀ tó dọ́nmọ́rán múlẹ̀ láarin ìjọba àtàwọn òsìsẹ́.

Nígbà tó ń gbóríyìn fún ìjọba lórí bó se ńsanwó osù àwọn òsìsẹ́ àtowó ìfẹ̀yìntì lórekóóre, ọ̀gbẹ́ni Sodo wá rọ Gómìnà Makinde láti tètè wánkan se sọ́rọ̀ owó osù tuntun, àwọn òsìsẹ́ tókéré jùlọ náà.

Kò sài tún kan sárá sí Gómìnà lórí bó se gbọ́rọ̀ àwọn òsìsẹ́ tíjọba tọ́kọjá gbasẹ́ lọ́wọ́ wọn yẹ̀wò, tó sì fún wọn nísẹ́ padà.

Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *