Yoruba

Temitope Bolugbe

Ida emi ara eni legbodo ti di gbomo gbomo laarin awọn ọdọ ode òní, o sí je ọnà kán tó ya sí ikú.

Gege bí àjọ eleto ìlera l’agbaye (WHO) se sọ, o jẹ ọnà kàn gbòógì tó n ṣokunfa ikú láàrín àwọn ọmọ ọdún marundinlogun sí ọmọ ọdún mokandilogbon l’agbaye ní ọdún 2019.

Ní k’ọpẹ k’ọpẹ yìí, ní akẹkọ kàn tó wà ní ìpele akọkọ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga fasiti ìpínlè Òsun, Salako Treasure, gb’emi ara rẹ nípa lílò nkan iseku pani lẹyìn ìgbà tí irẹwẹsi gba ọkàn rẹ.

Bakanna, ọkùnrin kan tí o jẹ ọmọ ọgbọ̀n ọdún, Usman Sani náà d’ẹmi ara rẹ legbodo ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ tí Babura ní ipinlẹ Jigawa.

Olóògbé náà ní ìròyìn n so pé o pokun so.

Ìròyìn tún tan nipa ti ọmọbìrin ajagun ojú òfurufú tó n ṣiṣẹ ní ilu-eko, ení ti wọn bá òkú rẹ ni ile’gbe rẹ , nibi tó ti pokunso ní ibùdó àwọn ọmọ ogun ojú òfurufú to wà ní Ikeja, ni ìlú Èkó.

Bí o bá ṣe opelope ọkan lára àjọ tó n dènà ìṣẹlẹ pajawiri ní ipinlẹ Èkó, bí ọkunrin ẹni ọdún meta-din-laadorin kan náà o bá ti gb’emi ara rẹ niyen nigba to gbìyànjú láti fo sinu òkun.

Ọkùnrin nà ṣé lalaye pé òun gbìyànjú láti gb’emi ara òun nítorí ọpọlọpọ ipenija èyítí tó n ba oun finra, to sì tí mùú òun’ ta awọn dukia rẹ bíi ilé, ilẹ ọkọ, ṣugbọn towó náà kò tán gbogbo ìṣòro rẹ.

Nigba to n gbé ọrọ yí yẹwo, onimọ nípa èrò ọkàn, ọmowé Oluwafisayo Adebimpe ṣàfihàn àwọn okùnfà dídá èmi ara ẹni legbodo leleyii ti o le jẹ aibori awọn idojukọ boya nínú ilé tàbí lẹnu iṣẹ.

Awọn ènìyàn kò rówó ná, ṣe bale’le tí’yawo bèrè owó oúnjẹ tàbí ìyále’le tí kò rise se, tàbí ẹni tó n w’oju ọmọ tí kò bímọ , tabi ẹni tó jáde ilé’we gíga tí kò rise, tàbí ẹnití àjálù ibí re lu, ti wọn gb’owo rẹ lọ tàbí tí ile-ise jona

Ewe, onimọ nípa èrò ọkàn náà wà gba awọn ẹbi, ara, ọrẹ àti ojúlùmò níyànjú láti joyè ojú lalakan fí n ṣorí ati pé kí wọn gbaruku ti awọn ènìyàn to wa layika wọn, ti wọn n la ìṣòro koja, tàbí àwọn tí wọn bá ti fa sẹyìn tàbí ṣe ainife sí àwọn nkán tó n lọ láwùjọ wọn.

Awọn ara ìlú Ìbàdàn náà fí èrò wón hàn lórí ìdí tí àwọn ènìyàn fi máa n d’ẹmi ara wọn legbodo.

Ti ìjọba ba pèsè iṣẹ, ti awọn ènìyàn bá rise ṣe, awọn ènìyàn kò ní ronú pé àwọn fẹ pokunso

Ti eniyan ba lọ kajọ, èrò k’ero má wá ṣọkan èèyàn

Àwọn ènìyàn náà gbà awọn tó n kojú irú ìṣòro bẹẹ láti wá ìrànlọ́wọ́ àwọn onímọ̀ nipa ẹrọ ọkàn, dokita nipa ìlera àti ẹni tí wón f’ọkan tan láti dènà awọn iṣẹlẹ to lè gb’emi wọn.

Bakanaa, Onimọ nípa èrò ọkàn , ọmowé Oluwafisayo Adebimpe, ni láti dẹ́kun dídá èmi ara ẹni legbodo, awọn ti ọrọ kàn yii, ní láti gba amoran lọdọ awọn tó mọ nípa èrò ọkàn fún ìtọ́nisọ́nà.

Subscribe to our Telegram and YouTube Channels also join our Whatsapp Update Group

Yoruba

Àjọ ton mojuto idagbasoke eto ìlera alabode nipinle Ogun pẹ̀lú ifowosowopo ìgbìmò tó ń risi ọrọ ìlera ojú nipinle náà tí sàgbékalè ètò ayẹwo ojú lofe fáwọn onimoto, ero àtàwọn aladani láwọn ibùdóko jákèjádò ìpínlè náà gẹ́gẹ́bí ara eto ton sàmìń ayajo ọjọ́ iriran tóko lọ́dún yi.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkòrí todun yi, tii se “nifẹ ojú rẹ, doola ẹ̀mí”, nibi ètò náà tó wáyé nilu Abeokuta, alága ẹgbẹ́ àwọn olùtọ́jú ojú eka tipínlè Ogun  Dókítà Oladapo Awodein ṣàlàyé pé igbelewon tí fihàn pé bí idà lọ́nà adota ìjàmbá ọkọ̀ ton wáyé je nípasẹ̀ airíran, idi niyi tó lómú ṣe kókó láti dojú kọ àwọn onímòto.

Nínú idasi alaga ẹgbẹ́ àwọn onímòto Igun Road Transport Employees Association of Nigeria ní Kútò, Olóyè Lanre Ladipo gbóríyìn fún ìjọba ìpínlè Ogun ló rii mímú ìtọ́jú ohun àbò àwọn onímòto lọkúkúndun pẹ̀lú ríro àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ẹ láti máa ṣètọ́jú ojú wọn boseto.

Alamu/Olaopa

Subscribe to our Telegram Channel and join our Whatsapp Update Group

Yoruba

Ègbé olùkọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì nileyi, ASUU tí sewele iyanselòdi olosu mejo rẹ pẹ̀lú àwọn afẹnukò ìlànà kan.

Alága ẹgbẹ́ náà fún olú ìlú wa Abuja, Ojogbon Kasimio Umar ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlè fáwọn akoroyin nilu Abuja. 

Ègbé náà pinnu láti fòpin sí iyanselòdi ohun lásìkò ìpàdé àwọn adarí tó bẹ̀rẹ̀ lalẹ àná eleyi tó parí laaro yi.

Ìpàdé ohun lẹgbẹ ASUU pé láti forí okoo sọọdúnrun lórí ìlànà tókàn lẹ́yìn tí igun ẹgbẹ́ ohun sepade lórí ìdájọ́ ilé ejo kotemilorun tó wáyé lose tó kọjá.

Taába gbàgbé pé ilé ẹjọ́ kotemilorun ló pàṣẹ fẹ́gbé ASUU láti sewele iyanselòdi tó gunle.

Ní báyì náà, àwọn ọmọ ìgbìmò ẹgbẹ́ náà leyi tari àwọn alaga ńipinle àtàwọn tokun ni wọ́n pèjù síbi ìpàdé náà tó wáyé lolu ilé isẹ ẹgbẹ́ ASUU nilu Abuja.

Alamu/olaopa

Subscribe to our Telegram Channel and join our Whatsapp Update Group

Yoruba

Ijoba Ipinle Ogun ti fi ipinnu re han lati mu atunto to wuyi de ba eka irin ajo afe atawon gbongan asa ibile pelu eron gba lati je  kowo to nwole si akoto oba nipinle ohun ko tubo rugoogo sii.

Alamojuto foro asa ati irin ajo afe nipinle Ogun Arabinrin Motunrayo Adeleke Oladapo lo siso loju oro oun lakoko too nforowero pelu akoroyin ileese Radio Nigeria nilu Abeokuta.

Arabinrin Motunrayo Oladapo eni to salaye pe,  eleda fi opolopo ibudo irin ajo afe  jinki ipinle Ogun bii, gbongan asa june 12, Ori Oke Olumo ati ibudo iyawe kawe Olusegun Obasanjo.

O salaye siwaju pe, akitiyan ti nlo lowo lati mu atunto to loorin  ba eka irin ajo afe nipinle naa.

Arabinrin Oladapo tenumo pe, ipinle Ogun lo nle waju ninu awon ipinle gbogbo leka eto asa,paapajulo nidi ipese aso adire.

Nigba to nsoro lori ayajo asa lagbaye fun ti Odun yi, alakoso  ro eka aladani lati fowosopo pelu ijoba Ipinle lati mu eka yi dun wo fun awon araalu.

O tun woye pe, irufe igbese oun,yoo je ki awon aralu  ni ife sawon ibudo irin ajo afe nipinle naa ati pe yoo tun ni ipa to dara lori oro aje ipinle naa.

    Olukemi Ogunkola

Subscribe to our Telegram Channel and join our Whatsapp Update Group

Yoruba

Ní itesiwaju ètò ìwóde tégbé òsìsé NLC gùnlé yíka orilede Nigeria, èyí tó ti wo ojó kejì bayii, Egbé náà atawon akegbé rè ti wode yíká ìlú Abuja loni.

 Ìròyìn sopé, lati nnkan bi ago méje òwúrò Òní lawon òsìsé ti peju- pese si unity Fountain feto ìwóde náà.

Níbáyìnáá, ètò àbò ti gbóná girigiri, ni tìbú- tòòòró ilè Asòfin àpapò ilè yí nilu Abuja, láti le pinwó ìwà jàgídí-jàgan to se e se ko rápálá wonú ìwóde Egbé NLC.

Akòwé àgbà Egbé NLC nílè yí, Ògbéni Emmanuel Ugboaja, sàlàyé pé ètò ìwóde náà lo n wáyé láti Fi sàtìleyìn fun ìyansélódì Egbé Asuu to nlo lówó, èyí tí won Fi gbe gbogbo àwon ilè Èkó gíga fásitì to n be nílè yí tìpa.

Ìwóde to wáyé lánàá ode yí, lawon ìpínlè kan, lo nope àkíyèsí ijoba àpapò si ìyansélódì olojo gbōoro tégbé Asuu gùnlé.

Ò tile lósù márùn-ún bayii, ti Egbé àwon olùkó lawon ilè Èkó gíga fásitì ilè yí atawon Egbé mín -ìn torokan leka ètò Èkó, tíwón ti gùnlé ìyansélódì, Lori èsùn bijoba àpapò se kùnà láti mu àdéhùn rè se fáwon Egbé náà.

Folakemi Wojuade 

Yoruba

Ètò ìwóde Egbé àwon òsìsé NLC ti wáyé yíká àwon ìpínlè lorilede yí.

 Ètò ìwóde náà tegbe àwon òsìsé gùnlé lo wáyé láti fi sàtìleyìn fun ìyansélódì Egbé ASUU to nlo lówó, tíwón si tún fi n sàfihàn àìdùnú lori owó tíjoba àpapò mórò ìyansélódì olósè méjìlá Egbé ASUU náà.

Àbò ìròyìn láti àwon ìpínlè bíi Èkó, Ògùn, Òndó, Òyó, Edo, Benue atawon ìpínlè mín-ìn torokan, sàfihàn bétò Ìwóde Egbé NLC se n lo, eyi tíwón ti gùnlé bayii káàkiri agbègbè.

Īko àwon oníròyìn wa, tó topinpin náà selo jábò pé, wámúwámú lawon àjo alaabo duro síbi tàwon ìwóde náà ti n wáyé, kawon jàñdùkú ma ba soòdi nnkan min-in mo won lówó.

Alága egbé àwon òsìsé lawon Ile Èkó gíga fásitì, ASUU tilé Èkó gíga fásitì ìbàdàn, Òjògbón Ayoola Akinwole, salaye pé, ètò ìwóde náà tàwon gùnlé, lawon fi n fi àìdùnú àwon hàn lori Ònà ti ijoba àpapò n gbà mórò ìyansélódì olósè méjìlá Egbé Asuu to nlo lówó ati lati Fi bèèrè, fún gbogbo ètò àwon.

 Nígbà tó n náà n sòrò, Alága Egbé Asuu tilé Èkó gíga fásitì ìmò-èro ládòkè Akíntólá nílùú Ògbómòsó, Òjògbón Biodun Olaniran, naa sàlàyé pé, ìyansélódì Òhún yóò mú àtúntò tó gbogbón bá ètò Èkó lawon Ile Èkó gíga fásitì ilè Nigeria, ti yóò sì tún dábò ò bo ojó òla àwon òdó.

Ní ti agbègbè Ìkejà nípìnlè Èkó ni ogunlógò àwon olùfèhónúhàn tígbà ìgboro kan pèlú òkanojokan àkolé lówó, nínú èyí tatiri, “e yé gbépo wolé látilè òkèrè mo” E sàtúse àwon ībùdó ìfopo wa, orilede Nigeria pe Ogota odún , Ebi si tún n pa araalu, e bawa wankan sesi.” 

Òrò ko yàtò nílùú Àkúré tii oluulu ìpínlè Òndó, Nibi teto ìwóde Egbé NLC ti nlo lówó ,tàwon olùfèhónúhàn náà si gbe àwon àkolé bíi, “O ti to get, e fopin si ìyansélódì Egbé Asuu to nlo lówó, kawon Omo wa le pada sile Èkó.

Net/ wojuade.

Yoruba

Baamòfin fun agbègbè Òkè- Ògùn, títún se, Agbejórò Àgbà nílè yí, Olóyè Jelili Owonikoko, ti sàpéjúwe Aséyìn tìlú ìséyìn to wàjà, Oba Abdulganiyu Adekunle, gégé bí  olórí tí gbogbo àwon èèyàn bòwò fun , tíwón si tún fenípò pelu, fún gbogbo àkókò to Lori àpèrè àwon baba ñla rè.

Nínú ìwé ìbánikédùn tó ko , lolóyè Owonikoko ti fìdí rè múlè pe, Ìdàgbàsókè àti Ògo loba Adekunle mú wo ìlú ìséyìn, èyí tómú kiwon mòó jákè-jádò àgbáyé.

Ó tókasí pe, lákòkóò ìsàkóso oba alaye náà nílùú ìséyìn, ni won Yan Onidajo Olukayode Ariwoola gégé bí Adelé Adájó àgbà nílè Nigeria.

Olóyè Owonikoko kò sàì tún soódi mímò pé, ní pa tòrò àwùjo , ìgbà Aséyìn tìlú ìséyìn to wàjà náà, nílùú tùbà- tùse, tígbà sìro gbogbo àwon èèyàn agbègbè ìlú ìséyìn lórùn , nínú èyí ti , àyípadà rere ti débá àsà , ìse , àti ilosiwaju ìlú ìséyìn.

Owonikoko/Wojuade

Yoruba

Bí igba ọdún dìẹ làwọn akẹ́kọ́ọ̀ ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ tó jóko sèdáwò àyẹ̀wò bákẹ̀kọ́ kan se gbéwọ̀n sí láti wọ ile ẹ̀kọ́ girama nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Alákoso fétò ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ̀nsì àti tìmọ̀ ẹ̀rọ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Rahman Abdul-Raheem ló kéde bẹ́ẹ̀ nílu Ìbàdàn, bẹ́ẹ̀ lósì fi ìdùnú rẹ̀ hàn lórí, bẹ́tò ìdánwò náà fún tọdún 2022 yíì se lọ yíká àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó ńbẹ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ lórúkọ, alákoso náà, akọ̀wé àgbà fún ilé isẹ́ ètò ẹ̀kọ́ nípinlẹ̀ yíì, arábìnrin Christianah Abioye sàpèjúwe bí ìdánwò náà se lọ ní ìrọ́wọ́ rẹsẹ̀, tí kò sì sí ìwà màgògágó kankan nínú ètò ìdánwò àsewọlé ilé lkọ́ girama náà.

Ó wá mú dáwọn òbí àtàwọn èèyàn àwùjọ lójú pé, ìjọba tó wà lóde báyíì setán láti dágbogbo àwọn ọmọ tíkò simile we padpa sébẹ̀ lábẹ́ ìlànà ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́

PR/Banjo/Wojuade

Yoruba

Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí níì gbé àwọn aláàjì láti orílẹ̀ èdè Saudi Arabia padà wa sílẹ̀.

Báàlù pẹ̀lú nọ́mbà ìmínimọ̀ xy7002 tó gbé àwọn aláàjì tó lé ní irinwó láti olú ìlú ilẹ̀ yí lọ gbéra kúrò ní pápá òfurufú ọba Abdulazeez tó wà ní Jeddah wá sí pápákọ̀ Nnamdi Azikwe nílẹ̀ yí.

Alága àjọ alaaji ilẹ̀ yí NAHCON, Àlhájì Zikrullah Hassan fàmì ìdánilójú yi hàn pé gbígbé àwọn alaaji wálé ni yi wáyé létò létò.

Àwọn tó wá láti ìpínlẹ̀ Borno àti Ọsun ni ìrètí wà pípé wọn yio gbéra kúrò ní orílẹ̀ èdè Saudi Arabia lóni nígbàtí àwọn ọmọ ilẹ̀ yí tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náà yio bẹ̀rẹ̀ wíwálé ní sísẹ̀ ǹtẹ̀lé lẹ́yìn tí wọ́n ti parí isẹ́ hajj wọn.

Ridwan Fasasi/Yemisi Owonokoko  

 

Yoruba

Àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ yí, INEC, ti pín àwọn ohun èèlò ìdìbò sáwọn ìjọba ìbílẹ̀ ọgbọ̀n ní ìpalẹ̀mọ́ fún ètò ìdìbò sípò Gómìnà tí yio wáyé nípinlẹ̀ Ọsun lọ́la.

Pínpín àwọn ohun èèlò ìdìbò ọ̀hún ló wáyé ní ọ́fìsì INEC, tó wà l’ósogbo níbití àwọn asájú ẹgbẹ́ òsèlú, àwọn oníròyìn àti ònwòye ètò ìdìbò péjú pésẹ̀ si.

Ọga àgbà àjọ INEC, nípinlẹ̀ Ọsun, ọ̀jọ̀gbọ́n Abdulganiyu Raji ni wọ́n kó àwọn ohun èèlò ètò ìdìbò lọ sáwọn ófìsì INEC, tó wà láwọn ìjọba ìbílẹ̀ pẹ̀lú ààbò tó péye.

Gẹ́gẹ́bí ọ́jọ́gbọ̀n Raji se sọ, àwọn ọ́gá àjọ INEC, àpapọ̀ márun àti àwọn lọ́galóga méjìlá láti àwọn ìpínlẹ̀ min ni wọ́n ti wà lárawọ́tó láti sàmójútó ètò ìdìbò láwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n yàn fún wọn.

Ọjọgbọn Raji sàla[yé wípé àwọn ìwé ìdìbò àti ibití wọ́n yio sàkọsílẹ̀ rẹ̀ si ni wọ́n se lára ọ̀tọ̀ fún ìjọba ìbílẹ̀ kànkan àti ibùdó, tó w;a fikun wípé àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tí òun ó ba buwọ́lù ni wọn ni gba wọlé bíì ojúlówó.

Net/Yemisi Owonikoko

 

Yoruba

Àarẹ ilẹ̀ America, Joe Biden ni yio se pàdépọ̀ pẹ̀lú àwọn adarí ilẹ̀ Palestine tí wọ́n wà lágbègbè West Bank lóni sáàjú kó tó lọ síbi ìpàdé àpérò ni Saudi Arabia.

Gẹ́gẹ́bí ohuntí àwọn ònwòye sọ, ó seese kí ǹkan lọ́ jái níbi ìpàdé náà pẹ̀lú Mahmoud Abbas nítorí gbúngbùngbún tó wà láàrin wọn pẹ̀lú ìsèjọba àarẹ Trump.

ọ̀gbẹ́ni Biden yio tún sèpàdépọ̀ pẹ̀lú adarí ilẹ̀ Saudi Arabia, Ọmọba Mohamined bin Salman àti bàbá rẹ, ọba Salman níbití wọ́n yio ti gíròrò lórí ìpèsè iná ọba, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀  lórí ọ̀rọ̀ ààbò.

Ao mu wá sí ìrántí wípé àarẹ Biden ti sèlérí a kojú oro sí orílẹ̀ èdè Saudi Arabia nítorí ìsekúpani oníròyìn Khasinoggi látọwọ́ àwọn òsìsẹ́ ilẹ̀ Saudi lọ́dún 2018.

BBC/Yemisi Owonikoko

Yoruba

Àarẹ Muhammadu Buhari ti kí ikọ̀ agbágbbọ̀ọ̀lù Super Falcons kú oríìre àseyọrí wọn nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú ikọ̀ Indomitable Lioness ti Cameroon pẹ̀lú àmì ayò kan sí òdo nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìpele kejì tó kángun sí àsekágbá níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ adúláwọ̀ tàwọn Obìnrin tọdún 2022 tó ńlọ ní Morocco.

Àtẹ̀jáde látọ̀dọ̀ amúgbálẹ́gbẹ àarẹ lórí ìròyìn àti ìpolongo, ọ̀gbẹ́ni Adesina ni àarẹ gbóríyìn fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Falcon fún bí wọ́n ti se jà fitafita láti ráàye nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tàwọn obìnrin tọdún tó ńbọ̀.

Bákanàà ni alákoso fọ́rọ̀ eré ìdárayá Sunday Dare nígbàtí ó yọ́ lórí àseyọrí àwọn agbábọ́ọ̀lù lóbìnrin rọ wọ́n láti túbọ̀ fikún ìsapá wọn láti jáwé olúborí fún ìgbà kẹwa nínú ìdíje tó lọ lọ́wọ́.

Oluwakayode Banjọ/Yemisi Owonikoko

Yoruba

Ijoba Ipinle Eko nipase ajo to n mojuto imototo ayika, LASEPA, ti ro awon eni orokan leka ipese nkan lori amojuto awon kemika to lewu.

Oga agba ajo LASEPA, Omowe Dolapo Fasawe, to soro naa lasiko eto idanileko awon eni-orokan nilu Eko, wa pe awon olupese nkan nija lati je akosemose lori ise ti won yan laayo, ki won si ri daju pe won le awon ti o kosemose kuro kole dekun awon aise deede.

Omowe Fasawe tenumo pe igbese naa yoo dekun isele biba ayika je.

O wa ro awon toro kan lati dekun iwa biba ayika je, pe oju lalakan fi nsori lori awon iwa ti koto ki dida kemika awon eroja min to lewu nu lona aito nipinle naa le dopin.

                                        Ayoade/Olaopa

Yoruba

Ile ise ijoba apapo to n ri soro igbokegbodo oko ti gunle eto didekun awon ibudo ti o bofin mu, ohun fifopin si iwa ajebanu lawon oju ona to lo sibudoko oju omi nilu Eko.

Akowe agba nile ise ohun, Arabinrin Magdalene Ajani to salaye pe ko din ni ibudo ayewo merindinlogbon ni ko ba ofin mu laarin ibudo ko oju omi Apapa si oju one ibudoko oju omi Sifa, sope awon eso alaabo ti won ko si be fun fifese abo mule ti so di anfani gbigba owo ko to.

Nigba to n baa won eni ofo kan forowero, lasiko ifilole eto ohun, Arabinrin Ajani sope o se Pataki ki joba fopin sawon ibudo ko ti ko bofin mu naa.

Arabinrin Ajani safikun alaye e pee to naa yoo seranlowo fun sise okoowo lawon ibuso ko oju omi atawon agbegbe to sun mo.

Ewe, ninu oro akowe agba ajo to n risi igbakegbodo oko oju omi, Ogbeni Emmanuel Jime, lo ti gboriyin fun le ise naa fun bose sagbekale iko to sapalemo awon aye ti ko bofin mu na loju ona ibudoko oju omi naa.

    Ayoade/Olaopa

Yoruba

Aare ile Igbimo Asofin agba ile yi, Omowe Ahmad Lawan ti sefilole igbimo eleni metala tah tana wadi bi won se nji eroja epo robi ati ipa re lori ipese epo ohun owo to n wole lori re.

O kede odo yi nibi ijoko ile.

Omowe Lawan wa kede Senator Bassey Alber-Akpan gegebi alaga igbimo naa nigbati senator Yusuf Yusuf, Solomon Adeola, Kabitu Gaya, Mohamed Aliero, George Sekibo ati Gebriel Suswam yio je omo igbimo re.

Awon yoku ni senator Ksahim Shettima, Aluyu Abdullahi ati Ndume, Sani Musa ati Ibrahim Gobir.

Igbimo yi ni won fun ni gbedeke osu kan lati pari ise iwadi won ti won si fabo je ile igbimo asofin naa nibi ijoko ile.

Net/Owonikoko

Yoruba

Bi awon omoleyin Kristi ile yi ti se darapomo awon akegbe won kaakiri agbaye lati sami iku Jesu Oluwa, ojise Olorun kan, Apostle Peter Akanji tipe fun emi ifaraeniji ati ife tawon adari.

Nigbati o nsoro lori Pataki ojo eti rere, Oludari ijo World Ourtreach Revival Center, WOREC nilu Ibadan ni ojo oni safihan ife to wa ninu kiku iku ifaraeni rubo Jesu faraye.

Apostle Akanji ni awon omo ile yi gbodo lo ayajo oni lati fi gbadura fun aanu ati iforiji ese lori bi won ti se nta eje alaise sile.

Apostle Akanji ni awon omo ile yi gbogbo jawo ninu pipani fetutu, iwa janduku ijinigbe ati awon iwa odaran to yorisi tita eje sile.

Kehinde/Owonikoko

Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀sun, ọ̀gbẹ́ni Adegboyega Oyetọla, ti síjú áànu wo àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kànlá tó wá láwọn ibùdó àtúnse ìlú Ilésà àti Ilé-Ifẹ, tó sì dáwọn sílẹ̀.

Gómìnà Oyetọla tó sanwó ìtanràn àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kànla náà lákokò àyẹ̀wò tó gbópọn lórí ẹ̀sùn wọn, sọ pé, ìgbésẹ̀ náà wáyé láti mú àdínkù bá báwọn ibùdó àtúnse náà seń kún lákunfàya.

Gómìnà Oyetọla ẹnití agbẹjọ́rò àgbà títún se alákoso fétò ìdájọ́ nípinlẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Fẹmi Akande sojú fún, rọ àwọn ẹlẹ́wọn tíwọ́n rí ìtúsílẹ̀ wọn gbà látọ̀dọ̀ Gómìnà ọ̀hún, láti máà se padà sẹ́sẹ̀ áàrọ̀ wọn, èyí tó tún lè dáwọn padà síbùdò àtúnse náà.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, igbákejì olùdarí ibùdó àtúnse nílu Ilésà, nípinlẹ̀ Ọsun, ọ̀gbẹ́ni Olosọla Amọran, gbóríyìn fún Gómìnà Oyetọla fún bó se tún mádikùn bá iye àwọn ẹlẹ́wọ̀n tón bẹ níbùdó ọ̀hún.

Folakemi Wojuade   

Yoruba

Ijọba àpapọ̀ ti sàwárí òsìsẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àtàbọ́, tójẹ́ pé ìwé ìgbanisísẹ́ ayédèrú ni wọ́n lò láti darapọ̀ mọ́ isẹ́ ìjọba.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí, ọ̀mọ̀wé Fọlasade Yẹmi-Ẹsan ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nílu Abuja.

Ọmọwe Yẹmi-Ẹsan sọpé ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àwọn èyàn tí wọ́n sàwárí ní ẹ̀ka ilésẹ́ kan, tí wọ́n sì rí ẹdẹ́gbẹta òsìsẹ́ ayédèrú láwọn ẹ̀ka min, lásìkò tí wọ́n ńse àyẹ̀wò.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí tọ́kasi pé, àwọn òsìsẹ́ tọrọ̀ náà kàn ni wọ́n yio yọ kúrò nínú ìlànà àtẹ ìsanwó olósoosù òsìsẹ́.

Folakemi Wojuade

Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ ti pè fún àmójútó tó péye láàrin àwọn tọ́rọ̀ kàn nídi àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò nílẹ̀ Nàijírìa.

Akọ̀wé àgbà iléesẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó wà fún ọ̀rọ̀ òsìsẹ́ àti ìgbanisísẹ́, Dókítà Yerima Peter-Tarfa ló pèpè yí nílu Abuja lásìkò ètò ìdánilẹ́kọ tó wáyé fáwọn olùdarí ẹkùn àti alámojútó láwọn ìpínlẹ̀ nípa ètò àtúntò ìlànà nípa àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò lórílẹ̀èdè Nàijírìa àti àwọn aláàlẹ fọ́dún 2021 sí ọdún 2025.

Ọmọwe Tarfa sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé ètò ìdánilẹ́kọ náà ló wà fún àgbéga ìmọ̀ àwọn olùkópa fún ilànà náà lórí àti fòpin sí lílo àwọn ọmọdé nílòkulò.

Ó wá rọ àwọn olùkópa pé kí wọ́n se àmúsẹ ìlànà náà, pẹ̀lú kíkópa tó jọjú nínú ìgbésẹ̀ àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò.

Babatunde Salaudeen  

Yoruba

Olúbàdàn tilẹ̀ ìbàdàn ọba Lekan Balogun ti sìkìlọ̀ fáwọn atọ́kùn ègùngùn, àtàwọn tó fẹ́ báwọn kọwọ ọdún pé kí wọ́n yàgò fún jàgídíjàgan lásìkò ayẹyẹ ọdún ilẹ̀ ìbàdàn tí yóò bẹ̀rẹ̀ lósù tó n bọ̀.

Ọba Balogun sàlàyé ọ̀rọ̀ yí lásìkò àbẹ̀wò alágbáà tíì se olórí àwọn egùngùn nílé olúbàdàn tó wà ní alárere.

Ọba alayé náà rọ alágbáà pé kí wọ́n ríì dájú pé wọ́n se ọdún náà pẹ̀lú ìrọ̀rùn , ó tẹnumọ́ pé áàfin olúbàdàn kò ní fáàyè gba ẹnikẹ́ni láti tàpá sí òfin nípa síse ọdún egúngún.

Olúbàdàn sèlérí pé, gbogbo àtìlẹ́yìn tó yẹ ni wọ́n yóò ri gbà láti áàfin fún àseyọrí ọdún náà.

Asáàjú àwọn ikọ̀ náà, ẹni tíì tún se alágbáà ti agúgù, ọ̀gbẹ́ni Ọjẹbiyi Adepọju sàlàyé wípé wọ́n se àbẹ̀wò sí áàfin olúbàdàn láti fi tó kábìyèsí láti wípé ìgbáradì fún ọdún egúngún tí yóò wáyé lọdún yí.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Òjò alágbára tó rọ̀ nílu’bàdàn lána òde yi ti ba àwọn ilégbe iléwe tófimọ́ òpó iná jẹ́.

Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria tó tọpinpin ìsẹ̀lẹ̀ náà, jábọ̀ pé òrùlé àwọn ilégbe kan lágbugbò Agbowó àti orogún ni ìjì ọ̀hún gbé lọ.

Yàtọ̀ fún àwọn ìgì tó wọ́lu ojú òpópónà, àwọn irinsẹ́ tón mú iná wọlé ilésẹ́ IBEDC náà ló tún di bíbàjẹ́.

Ilésẹ́ Radio Nigeria tún wóòye pé àwọn ilé ńmú ilé ìwé orogún Girammer school ni óbàjẹ́ kọjála.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú olùgbé méjì ní orogún, ọ̀gbẹ́ni Sakiru Iyanda àti ọ̀gbẹ́ni Kazeem Ọladẹjọ sọ wípé òjò náà ti ba ọ̀pọ̀ ǹkan jk ládugbò, tí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ síjọba láti sètò ìrànwọ́ fáwọn tó ní ilé tí òjò bàjẹ́, ní kìakìa.

Famakin/Afọnja

Yoruba

Àwọn ẹlẹ́ri Jèhófà nílẹ̀ yí àti káàkiri àgbáyé ni wọn yio si gbọ̀gàn ìpàdé wọn padà lọ́jọ́ ẹtì ọ̀sẹ̀ yí lẹ́yìn tí wọ́n ti gbéè tì padà fún bíì ọdún méjì níbamu pẹ̀lú ìlànà áàbò àti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn covid 19.

Àtẹ̀jáde látọ̀dọ̀ olú ile isẹ́ àwọn ẹlẹ́ri Jèhóvàh sọ wípé àkànseàsọyé ọlọ́gbọ̀n ìsẹ́jú tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “ Níbo láti léè ríì ìrètí tó dájú”ni yio wáyé láwọn gbọ̀ngàn ìpàdé káàkiri àgbáyé.

Àtẹ̀jéde náà wá rọ àwọn ènìyàn láti péjú pésẹ̀ fún àkànse ètò ìrántí ikú Jésù Olúwa ní àsálẹ́ ọjọ́ ẹtì ọjọ́ kéèdógún osù tónbọ̀.

Àtẹ̀jáde náà fikun wípé ko sí ètò ìforúkọsílẹ̀ fáwọn ètò méjèèjì wọ́nyí, bí Wọ́n bá si fẹ́ ìdáhùn si ìbéère lórí àwọn ètò wọ́nyí wọ́n léè rí lóri àtẹ ẹ̀rọ ayélujára ni ìtàkùn www.jw.org.

Nafiu Busari/Oluwayemisi Owonikoko

Yoruba

Ilésẹ́ tón rísí ìrìnà ojú irin ti fòfinde ìrìnà láti Abuja lọ sí Kaduna, tí kò sì ní gbèdéke.

Ilésẹ́ náà ló jẹ́ kọ́rọ̀ yí di mímọ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó fi síta lójú òpó abẹ́yẹ fò twitter rẹ̀ lóòrọ yi.

Ó sọ pé ìfòfindè náà ló wáyé fún àwọn ìdí tí wọ́n kò lérò, tó sìní wọ́n yo sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ láipẹ.

Ilésẹ́ náà tún sọpé àwọn agbésùnmọ̀mí kan tún ju àdó olóró sí ojúrin Abuja lọ sí Kaduna, tí wọ̀n sì kojú ọkọ̀ ojúrin tó ní ọ̀pọ̀ èrò nínú lálẹ́ ọjọ́ ajé.

Bákanà ni wọ́n filéde pé àwọn ilésẹ́ alábo ti lọ sí ibi ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Ikọ̀lú ọ̀hún ló wáyé, lẹ́yìn ọjọ́ diẹ, táwọn agbésùmọ̀mí kọlu pápákọ̀ òfurufú Kaduna, níbití wọ́n kò ti fàyè gba kí ọkọ̀ báàlù kó fóò.

Ololade Afọnja 

Yoruba

Igbákejì Àrẹ, Yẹmi Ọsinbajo ti kéde ìdásílẹ̀ ètò ìdàgbàsókè mẹ́fà èyí tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ gùnlé láwọn lẹkun kọ̀kan nílẹ̀ yí, láti lè mú kí àgbéga débá ọrọ̀ ajé láwọn  ìpínlẹ̀.

Igbákejì Àrẹ kédeyi lásìkò àpérò ilẹ̀ adúláwọ̀ níbi tí àtúntò fọ́dún 2022 yo ti wáyé nílu Abuja.

Ọjọgbọn Ọsinbajo sọ fún àwọn akópa pé ìbásepọ̀ tó sodo sínú ètò ìdàgbàsókè ọ̀hún ni yo fún ilẹ̀ Nàijírìa ni ánfaní pẹ̀lú bí o se ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyàn, ilẹ̀ tófimọ́ oníruru ẹ̀yà.

Ó sọ síwájú pé ètò náà ni yo mú kí ètò ọrọ̀ ajé lánri àwọn ìjọba lágbayé, láti lè mú kí áàlá rere wá sí ìmúsẹ gẹ́gẹ̀bí àjọ ìsọ̀kan àgbáyé se ti láà kalẹ̀.

Ololade Afọnja