Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ sọ àsọyánlórí ìpèsè óunjẹ

Alákoso fétò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè àwọn agbègbè, ọ̀gbìn Sabo Nanono sọpé, ilẹ̀ Nàijírìa ńpèsè óunjẹ́ tootoo, láti bọ́ àwọn èèyàn rẹ̀, tí yóò sìtún ma kólọ sáwọn orílẹ̀dè alámulégbé rẹ̀.

Alákoso náà sọ̀rọ̀ yíì nígbà tó ńbá àwọn oníròyìn sọ̀rs nílu Abuja, lórí àyájọ́ óunjẹ lágbayé.

Ó fikun pé ìjọba àpapọ̀ ti pinu láti ti gbogbo àwọn ẹnu bodè ìlú yíì paapaa fáwọn orílẹ̀dè alámulégbé tó ti sọ ilẹ̀ Nàijírìa di ibùdó tíwọ́n ńkó àwọn ìrẹsì àtàwọn ọjà min-in tọ́jọ́ ti lọ lórí wọn si.

Kẹmi Ogunkọla/Ọmọlọla Alamu

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *