September 21, 2020
News

Ìjọba àpapọ̀ sún ìdíje eré ìdárayá àpapọ̀ ilẹ̀ yí síwájú

Àarẹ Muhammadu Buhari ti fọwọ́sí ìsúnsíwájú ìdíje eré ìdárayá àpapọ̀ ilẹ̀ yí ogún iruẹ̀ tó yẹ kí ó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ ìakú ọ̀sẹ̀ tón bọ̀ nípinlẹ̀ Edo sí ọjọ́ min ọjọ́ ire.

Gẹ́gẹ́bí alákoso fọ́rọ̀ ọ̀dọ́ àti eré ìdárayá, Sunday Dare se sọ lórí ojú ewé abẹ́yẹfò rẹ̀, ó ní ìsúnsíwájú yi jẹ́ ara ìgbésẹ̀ láti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn covid 19.

Ọgbẹni Dare ní ìpàdé ti wáyé láàrin àwọn tọ́rọ̀ gbọ̀ngbọ̀n lórí ọ̀rọ̀ covd 19 àti àwọn tọ́rọ̀ ìdíje eré ìdárayá àpapọ̀ ilẹ̀ yí kan nílé isẹ́ ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ìlera lórí ìsúnsíwájú ìdíje náà.

Ó fikun wípé Àarẹ Buhari ti buw alu ìsúnsíwájú yi lẹ́yìn tí wọn ti fi bí ọ̀rọ̀ ti se ńlọ tọ́ọ̀ lẹ́yìn ìpàdè tó wáyé.

Ọlaoluwa Fawọle/Dada Yẹmisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *