September 21, 2020
Yoruba

Ìpínlẹ̀ Benue ńgbèrò ikọ̀ aláàbo tuntun

Gómìnà Samuel Ortom ti ìpínlẹ̀ Benue ti ní ìjọba tí òun léwájú rẹ̀ yio gbé ikọ̀ aláàbo bii ti àmọ̀tẹ́kùn kalẹ̀ nípínlẹ̀ rẹ̀ nítorí ìpèníjà ńlá tó ńkojú ètò áàbò ibẹ̀.

Gómìnà ẹniti yán ọ̀rọ̀ yi nílu Makurdi ni ó ti sepàtàkì láti sàgbékalẹ̀ ìní ikọ̀ aláàbo yi láti kún isapa àwọn àjọ ẹ̀sọ́ aláàbo nípinlẹ̀ náà.

Ọgbẹni Ortom ni wọ́n ti tẹ́ pẹpẹ ọ̀rọ̀ yi níwájú àwọn Gómìnà áàrin gùngùn àríwá ilẹ̀ yi àmọ́ ó jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ìpínlẹ̀ Benue yio nílò láti gbé lásìkò yi.

Mnt/Dada Yẹmisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *