Ẹnìkan ti gbẹ́mimì, toopo ọkọ̀ sijona guuguu níbi ìbúgbàmù ọkọ̀ epo pẹtiro èyí tówáyé nílu Abẹokuta olú-ìlú ìpínlẹ̀ Ògùn.

Ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lówáyé lórọ òní, lójú òpópónà boulevard tójẹ́ tìjọba àpapọ̀.

Ìròyìn sọdi mímọ̀ pé, ìbúgbàmù ọ̀hún ló wáyé pẹ̀lú ọkọ̀ agbépo ńlá lẹ́yìn tó sọ ìjánurẹ̀nù

Arigbọ́ pé ọkọ̀ agbépo ọ̀hún ló ńbọ̀ láti ọ̀nà Sàgámù –òkè Mosan, tósì sọ ìjánu rẹ̀ nù lásìkò tó sọ̀kalẹ̀ lórí afárá olóòkè.

Ọkọ̀ agbépo kọ́ọ̀lu alùpùpù kan, kotóò lóò yáà bá àwọn ọkọ̀ akérò tó ńdúró fún èrò nísàlẹ̀ afárá ọ̀hún.

Iná ọ̀hún ló ran lọ sáwọn ọ́fìsì lágbègbè náà, tó sì mu ìbẹ̀rù bojo báà àwọn awakọ̀, tí wọ́n ńsá àsálà fẹ́mi wọn kí iná náà má báà múwọn.

Títí di àsìkò tí wọ́n ńkọ ìròyìn yíì jọ, àwọn òsìsẹ́ alábo wa lágbègbè náà láti mú ètò ìrìnà rọrùn.

Oluokun/Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *