Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ti pàsẹ ìgbétìpa àwọn ilé-ìwé mẹ́tàlá kan tíwọ́n wà láwọn agbègbè táwọn agbébọn sáabà máà ńkọlù lẹ́yẹ ò sọkà.

Èyí ló wáyé nípasl báwọn agbébọn se lọ kọlu ilé-ìwé Bethel Baptist tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Chikun nípinlẹ̀ Kaduna, níbití wọ́n ti àwọn akẹ́kọ́ọ̀, tíwọ́n ko tile sọ iye wọn ní pàtó, ko lọ.

Olùdarí àgbà pátápátá tó wà lẹ́ka tásẹ, gbogbo tin jéde nílesẹ́ tó ń rí sọ́rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ nípinlẹ̀ náà, arábìnrin Umma Ahmed ló pàsẹ náà fún gbogbo àwọn olùdásílẹ̀ àwọn ilé-ìwé aládani láti gbé àwọn ilé ìwé wọn tìpa lẹ́yẹ ó sọkà, pẹ̀lú àfikún èyíkèyí iléìwé aládani tó bá kọ́ tí ogbo sasẹ náà, yóò fojú winá òfin.

Lẹ́nu lọ́lọ́ yíì nípinlẹ̀ Kaduna ti ń fojú winná ọ̀kanòjọ̀kan ìkọlù látọ̀dọ̀ àwọn agbèbọn nínú èyí táwọn ilé-ẹ̀kọ́ tijẹ́ àfojúsùn wọn.

Net/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *