Àarẹ ilẹ̀ South Africa nígbà kan rí, Jacob Zuma ti fa ara rẹ̀ lé àwọn ọlọ́pa lọ́wọ́ láti sẹ̀wọ̀n osù mẹẹdogun tílé ẹjọ́ dá fún un lórí ẹ̀sùn pé, ó kọ ti ọgbọn in sí ipe ilé ẹjọ́.

Ó fa ara rẹ̀ lé àwọn agbófinró lọ́wọ́ nínú ilé rẹ̀ tó wà lẹ́kun Kwazulu-Natal.

Ileesẹ ọlọ́pa ló ti kọ́kọ́ sèkìlọ̀ wí pé àwọn ti setán láti fi kélé òfin gbe ní tipá típa tó bá kùnà láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lóru mọ́jú.

Lọ́sẹ̀ tó kọjá nílé ẹjọ́ gbé ìdájọ́ àwọn osu mẹẹdogun ka le fún Zuma nítorí pé ó kùnà láti farahàn nílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn síse owó ìlú kúnmọkùnmọ.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *