Yoruba

Ìyansẹ́lódì Áwọn Dókítà: Ìjọba Àpapọ̀ Kéde Òfin Óò Sisẹ́ Óò Gbowó

Ìjọba àpapọ̀ ti páà lásẹ fún àwọn ọ̀gá ilé ìwòsàn tó jẹ́ tìjọba pé kí wọ́n se àmúsẹ ìlànà òfin óò se, óò gbowó osù fáwọn dókítà tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àwọn onímọ̀ ìsègùn òyìnbó tó n kọ́ ẹ̀kọ́ mọ́ ẹ̀kọ́ táà mọ si Resident Doctors.

Àsẹ t’íjọba fi síta yi ló wà nínú ìwé tí olùdarí ètò àwọn ilé ìwòsàn níléèsẹ́ ètò ìlera ìjọba àpapọ̀ Dókítà Adebimpe Adebiyi fọwọ́sí.

Dókítà Adebiyi sàlàyé wí pé iléèsẹ́ náà ti gba ìwé látọ̀dọ̀ iléèsẹ́ óò sisẹ́, óò gbowó àti ìgbanisísẹ́ wípé òfin náà pé kí wọ́n ó se àmúsẹ rẹ̀.

Babatunde Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *