Yoruba

Gomina Abiodun Di Ebi Ijamba Oko Oju Popo Ru Agbasese Lopopona Naa

Gomina ipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun ti soo di mimo pe agbasese to n se ise atunse opopona marose Ibadan ati Eko lo ye ki won di eti ru lori aipese ami ewu sawon opopona naa leyi to ti n se okunfa ijamba oko lemolemo lenu ojo meta yi lopopona marose naa.

Omooba Dapo Abiodun sipaya oro yi lasiko abewo lenu ise to se sibi ijamba oko elepo to gbina, leyi to ran eeyan marun sorun apapandodo lenu iloro Ogere nipinle Ogun.

Gomina Abiodun eni to toka sip e eto aabo ko gunmo lopopona marose naa, o wa kesi agbasese to n se ise lopopona naa pe ko tete se ohun to be ye.

Nigba to n kedun pelu awon to padanu ebi won sibi ijamba ina naa, Gomina Abiodun to awon awako pe ki won maa feso se loju popo.

Ayodele Olaopa

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *