Awon olugbe ilu’Badan ti kesi ijoba lati wojutu si owongogo epo pentrol to n faalee.
Won soro yi lasiko ti won n ba akoroyin ileese Radio Nigeria to n topinpin isele owongogo epo naa.Lara awon olugbe ohun, koroju si bawon ile epo se n ta oja, laarin igba naira si igba le ladota naira, eyi to yato gedegbe is iye jala epo kan tise marundinladosan naira.
Awako kan, Ogbeni Mukaila Oladimeji salaye pe ile epo ni oun sun si, koun le ri epo ra, bakanna olugbe meji miran, Ogbeni Ade Bola and Arabinrin Bola Adeoti sapejuwe owongogo epo gegebi inira ti ko se farada, pelu bawon se n ra epo lodo awon to n ta lona aito loju opopona.
Nibayinaa, owo oko lo ti lewo sii larin ilu Ibadan pelu ida ogoji ninu ogorun.
Okareh/Afonja


