Egbe awon obinrin oniroyin nile nigeria NAWOJ eka tipinle ogun ti gba awon obi niyanju pe ki won kilo fawon omo won lori gbigba ebun ofe to lee ko won siyonu laako ayeye ayajo ololufe.
Ipolongo ilaniloye naa lo gbe awon omo egbe NAWOJ lo sile ijosin lolokan ofokan pelu awon oja nilu Abeokuta.
Nigba to n bawon ontaja soro loja lafenwa alaga egbe NAWOJ nipinle ogun arabinrin Modupeopla Sobukola salaye wi pe eto ilaniloye naa se pataki lati fi la awon odo kuro ninu ewu didi oloro ojiji.
Arabinrin Sobukola tenumo idi to fi ye kawon obi naa topase irinsi awon omo won nigba gbogbo, ki won ma baa bo si panpe awon apani setutu ola to gbode.
Ninu oro re, Babaloja Lafenwa, Oloye Mukaila Adeyinka dupe lowo egbe obinrin oniroyin fun igbiyanju won leyi ti yoo ta awon obi ji giri sojuse won.
Sobukonla / Salaudeen