Yoruba

Gomina Oluwarotimi Akeredolu ti Ipinle Ondo ti jeje atileyin gbogbo igba fun ile ise Ologun 32 Artillery Brigade to wa ni Owena nilu Akure nidi kikapa iwa odaran nipinle naa.

Gomina Akeredolu soro atileyin yin lasiko to n gbalejo oga agba tuntun ti won sese gbe wa Brigadier General Raymond Utasaba lofisi re.

Gomina gboriyin fun ile ise omo ologun fun ipa ribiribi ti won nko lori oro aabo ni ipinle naa.

O war o ogagun tuntun naa lati fowosowopo pelu awon ajo eleto aabo yoku lati tubo kappa iwa odaran.

Saaju ni Oga to nkuro nibe, Brigadier General Zakare Abubakar ti moriri atileyin ijoba ipinle naa fun ile ise omo ologun ni paapajulo fun awon opo awon to subu loju ija to wa beere fun iru atileyin bee feni to gba ipo lowo re.

Gomina Akeredolu tun gbalejo igbakeji oga agba fun ile ise olopa tuntun fun ekun ketadinlogun to wa fun ipinle Ondo ati Ekiti, Ogagun Isaac Akinmoyede.

Nigbati on fi aidunu re han lori isele ijinigbe, idigun jale, ifipabani lopo ati iwa janduku to ti di toro fonkale nipinle Ondo, Ogbeni Akinmoyede beere fun ifowosowopo laarin awon olopa awon ajo eleto aabo yoku ati awon ara ilu lati lee yanju awon isoro wonyi.

 Olorunferanmi Odofin/Oluwayemisi Dada

Security

Governor Oluwarotimi Akeredolu has pledged his continual support for the 32 Artillery Brigade, Owena Cantonment in Akure with a view to combating crime in Ondo State.

Governor Akeredolu made the pledge while receiving the newly posted Brigade Commander, Brigadier General Raymond Utsaha in his office.

The governor commended Nigerian Army for the immense contributions to the security of the state.

Governor Akeredolu, however, encouraged the new Brigade Commander to cooperate with all sister security agencies to further nip crime in the bud.

Earlier, the former Brigade Commander, 32 Artillery Brigade, Brigadier General Zakare Abubakar, who recognized the state government’s support to the military especially on the care for widows of the fallen heroes sought similar cooperation for his successor, Brigadier General Raymond Utsaha.

Brigadier General Abubakar attributed his transfer to the expiration of his two-year tenure in Owena Cantonment.

Olorunferanmi Odofin