Yoruba

Ijoba Ipinle Eko nipase ajo to n mojuto imototo ayika, LASEPA, ti ro awon eni orokan leka ipese nkan lori amojuto awon kemika to lewu.

Oga agba ajo LASEPA, Omowe Dolapo Fasawe, to soro naa lasiko eto idanileko awon eni-orokan nilu Eko, wa pe awon olupese nkan nija lati je akosemose lori ise ti won yan laayo, ki won si ri daju pe won le awon ti o kosemose kuro kole dekun awon aise deede.

Omowe Fasawe tenumo pe igbese naa yoo dekun isele biba ayika je.

O wa ro awon toro kan lati dekun iwa biba ayika je, pe oju lalakan fi nsori lori awon iwa ti koto ki dida kemika awon eroja min to lewu nu lona aito nipinle naa le dopin.

                                        Ayoade/Olaopa

News Yoruba

Igbimo to nri si sunkere fakere oko nipinle Eko, LASTMA ti kede titipa oju ona Ahmadu Bello si Adeola Odeku to fi mo Adetokunbo Ademola.

Alakoso agba fun igbimo LASTMA, Ogbeni Bolaji Oreagba so eyi ninu atejade kan nilu Eko.

Atejade ohun ni oju opopona ohun yoo je titipa fun igba die, ti lilo bibo oko yoo si je didari si ibomiran.

Bakanna latejade naa tun sope awon ona miran yoo je mimojuto botiye, lati madinku ba idiwo yoowu.

Ijoba ipinle Eko kede igbetipa  oju opopona Ahmadu Bello.

Net/Idogbe

Yoruba

Ijoba ipinle Eko ti ya owo to le ni billionu kan naira soto fun eko o fe lodun 2021, fun awon to je omo bibi ipinle Eko to w anile eko giga yika ile yi.

Akowe agba fun ileese to n mojuto eko ofe nipinle Eko, Ogbeni Omotayo Fakolujo soro yi lasiko to n baa won akoroyin soro lori ise eyi ti won ti gbee, lati igbati o ti de ori ipo.

Ogbeni Fakolujo yan oro pe ileese naa ti bere sini se abewo sawon ileewe giga to wa nipinle Eko ati lawon ipinle yooku lati le ri daju pe opo akeko je igbadun anfani yi.

O tokasi pe isejoba Gomina Sanwo-Olu lo n  sise, lati ri daju pea won omo  bibi re, ri anfani si eto eko to muna doko, o fikun pee to eko ofe naa ni won ti se ifilole re fun awon akeko to wa nipele ileewe eko alakobere ati girama.

Ololade Afonja 

Yoruba

Ijoba ipinle Eko ti salaye igbaradi re ati se atungbende ofin to de awon to n fi okada gbe ero.

Alakoso eto iroyin fin Ipinle Eko, Ogbeni Gbenga Omotoso lo kede oro yin ni Ikeja pelu alaye wi pe, ofin eto irina Ipinle Eko todun 2018 lo fofinde igbokegbodo awon to n fi okada gbe ero lawon agbage kan ni ipinle naa.

Ogbeni Omotoso tenumo pe laipe ni ijoba ipinle naa yoo gbe igbese to nipon lori oro awon olokada.

Ogbeni Omotoso war o awon iko to nto pinpin eto irinna oju popo nipinle Eko pe ki won jigiri si ojuse won nipa atileyin ati liana ni tele fun ipinle naa lori ati wagbo dekun fun awon to n fi okada gbe ero.

Salaudeen