Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, ọmọba Dapọ Abiọdun ti fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé òun kò ní dín owó osù àwọn òsìsẹ́ kù, pẹ̀lú ìpèníjà tón dojúkọ ètò ọrọ ajé nílẹ̀ yí.
Gómìnà Abiọdun sọ̀rọ̀ ìdánilójú yi nílu Abẹokuta lásìkò tón sínu pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ́ òsèlú All Progressive Congress APC, nílu Abẹokuta.
Óní ìsèjọba òun, yo tẹ̀síwájú láti ma sisẹ́, tí ètò ọrọ ajé ìpínlẹ̀ náà yo fi túnbọ̀ gbópọn si, láti le se isẹ́ ìríjú tó yẹ fún àwọn arálu.
Ọmọba Abiọdun wá sèlérí pé ètò ìdìbò sípò nìjọba ìbílẹ̀ tón bọ̀ nínú osù keje, lọ́jọ́ kẹrin lé lógún yíká ìpínlẹ̀ náà, ni kòní ní kọ́ninkọ́họ kankan nu.
Sherifdeen/Afọnja