Yoruba

Aarẹ Buhari sìde ètò ìdánilẹ́kọ fáwọn alákoso tuntun

Bí àwọn alákoso tuntun tí yóò lakoko iléesẹ́ ìjọba kọ̀ọ̀kan se ǹgbaradì fún ètò ìbúra wọn tí yóò wáyé lọ́jọ́rú ọ̀sẹ̀ yi, wọ́n wà níbi ètò ìdánilẹ́kọ ìtọ́nisọ́nà sáájú isẹ́ ọlọ́jọ́ méjì kan nílu Abuja.

Nígbà tó ńside ìdánilẹ́kọ náà, àarẹ Muhammadu Buhari tó kí àwọn tórísáyàn sípò alákoso náà, kú oríìre bẹ́ẹ̀ ló sì késí wọn àti sísepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́nu ìgbésẹ́ gbogbo tí ìjọba ńgbé láti fọ gbagun ìsk àti àiní dànù kúrò láwùjọ ilẹ̀ yíì.

Àarẹ Buhari fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe, àkoso rẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó pọ̀ nínú àwọn èèyàn náà láti mú kí àwọn ètò àfojúsùn rẹ̀ fún mímú orílẹ̀èdè yíì dé ìpele gíga.

Sáajú ni akọ̀wé ìjọba àpapọ̀, ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha tí kókó bá àwọn tí yóò bọ sípò alákoso lọ́kan ò jọ̀kan náà sọ̀rọ̀ láti fara wọn jìn fún ìgbáyégbádùn aráalu.

Lára àwọn tó wà níbi ètò náà ni igbákejì Àarẹ, ọ̀jọ̀gbọ̀n Yẹmi Ọsinbajo, àwọn Gómìnà látàwọn ìpínlẹ̀ kan àti olórí òsìsẹ́ lọ́fììsì àarẹ, ọ̀gbẹ́ni Abba Kyari.

Léyi tí àarẹ síde ìpàdé náà tan ni àwọn olùkópa wọ yẹ̀wù lọ láti bẹ̀rẹ̀ ètò lójú méjèèjì.

Babatunde Tiamiyu

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *