Yoruba

Ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn eré ìdárayá dìbò yan adárí tuntun

Ẹgbẹ́ àwọn akọ̀ròyìn eré ìdárayá nílẹ̀ yíì, SWAN, ti sàtúnyàn àarẹ wọn tẹ́lẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Honour Sirawooo gẹ́gẹ́ bí àarẹ fún sáà kejì.

Ọgbẹ́ni Sirawoo jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò ọlọ́dún mẹ́ta-mẹ́ta ẹgbẹ́ náà, tówáyé  nílu Portharcourt nípinlẹ̀ Rivers.

Ọgbẹ́ni Seun Ajayi-Obe tó ti fìgbàkan rí jẹ́ alága ẹgbẹ́ SWAN, nípinlẹ̀ Ọyọ, làwọn ọmọ égbẹ́ dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí igbákejì àarẹ fún ìwọ̀ọ-oorùn gúusù ilẹ̀ yíì.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ àarẹ Sirawoo sọpé ètò ìgbáyégbádùn àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lòhun yóò mu lọ́kunkúndùn.

Àwọn asojú láti ìpínlẹ̀ ọgbọ̀n àti olú-ìlú ilẹ̀ Abuja ló péjú síbi ètò ìdìbò náà.

Kẹmi Ogunkọla/Fawọle

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *