Yoruba

Àjọ EFCC, kéde wíwá òsìsẹ́ bánki kan fẹ́sùn ìwà ìbàjẹ́

Àjọ tó ńgbógunti ìwà ìbàjẹ́ àti síse owó ìlú kúmọ-kùmọ, EFCC, ti kéde wípé àwọn ńwá, òsìsẹ́ tẹ́lẹ̀ ní bánki aládani kan, Mayọwa Onabanjọ, fún lílọ́wọ́ nínú lílu bánki àpapọ̀ ilẹ̀ yíì, tìlú Ìbàdàn.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí olùdarí lẹ́ka ìbáráalu sọ̀rọ̀ nílesẹ́ náà, ẹkùn ìbàdàn, ọ̀gbẹ́ni Jide Jẹgẹdẹ fisíta sọpé, ẹnití wọ́n fura sí náà, niwọ́n ti fìgbàkan rí gbé lọ sí ilé-ẹjọ́ lọ́dún 2015, tí wọ́n gba óniduró rẹ̀ kótódipé ó sálọ.

Ọgbẹ́ni Jẹgẹdẹ wá sọpé, irọ́ tójìnà sotọ́ọ̀ làhesọ ọ̀rọ̀ tó ńlọ láwùjọ wípé àwọn owó tóyẹ kójẹ́ sí sún tóníse pẹ̀lú ẹjọ́ jìbìtì ọ̀hún tó wà ní ilésẹ́ EFCC, ti di ǹkan miran.

Ó wá sọ́di mímọ̀ pé, àwọn àwọn ọmọ náà kòsí ní abẹ́ àkóso ilésẹ́ EFCC.

Lọ́dún 2014, làwọn òsìsẹ́ ilé ìfówópamọ́ tóótóó ọgbọ̀n níyéè, jẹ́ fífẹ̀sùn kàn wípé wọ́n lọ́wọ́ nínú lílu jìbìtì owó tóyẹ kójẹ́ bíbàjẹ́ nílesẹ́ bánki àpapọ̀ ẹkùn Ìbàdàn.

Kẹmi Ogunkọla/Olarinde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *