Ilé ìgbìmò asofin ìpínlè Ọ̀yọ́ ti rọ ìgbìmò Aláṣẹ ìpínlè yi láti pàṣẹ ilé isẹ tó wà foro àwọn obìnrin láti tètè gunle àwọn ètò ilaniloye lórí ewu tó wà nidi ìwà jagidi jagan láàrín àwọn ọmọdé láwùjọ.

Níbi ìjóko ilé àkọ́kọ́ fún todùn yi, àwọn asòfin fi aidunu wọn hàn lórí bíi ìwà ọ̀daràn ṣe ngogo sii láàrin àwọn ọmọ ilé ìwé ńipinle yi leyi tí wọ́n di ẹbi rẹ ru àìní ẹ̀kọ́ ilé tó péye láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí.

Ọ̀rọ̀ yi ló wáyé lẹ́yìn àbá tí asòfin tó ńsoju àríwá Ogbomoso, arábìnrin Wunmi Oladejo gbé wà síwájú ilé lórí ìdí tó fi yẹkí àwọn ìgbìmò Aláṣẹ tètè gbé ìgbéṣe láti mú adínkù bá ìwà ọ̀daràn láàrin àwọn ọmọdé.

Nígbàtí ó ń gbé àbá náà kalè arábìnrin Oladeji daba pé kí wọ́n túbọ̀ sedasile àwọn ibùdó àtúnṣe fún ìní àwọn ọmọdé bẹ́ẹ̀ sì pẹ̀lú àwọn irinse tó péye.

Nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀, Alága ilé ìgbìmò asòfin, ógbéni Debo Ogundoyin ro ìjọba láti túbọ̀ kò àwọn ilé ìwé síí pẹ̀lú àwọn. 

Iyabo Adebisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *