Yoruba

Ile Iwosan Nla UCH Fofin de Lilo Bibo Oko Lati Dena Covid-19

Ile iwosan nla ekose isegun UCH, Ibadan ti fofinde lilo-bibo oko ninu ogba ile iwosan ohun lati dena ajekale arun Covid-19 nipinle Oyo.

Ninu atejade kan ti oludari eto gbogbo nile iwosan na fisita, Ogbeni S.O. Oladejo sope igbimo alakoso tipalase pe awon osise toni oko tarawon tiwon situn leeyan tongba itoju nile iwosan na nikan ni won yio gba laaye lati wole lojuna ati gbogun ti itankale kokoro arun coronavirus ninu ogba ile iwosan na.

Atejade ohun tun fidire mule pe iwonba osise ni won yio gba laaye lati wole pelu akole pelebe tiwon ko oruko ile iwosan oun si lara.

Akosile ti Ajo ton bojuto idena itankale arun nileyii fisita sope kodin ni ogoji eniyan toti lugbadi arun na, awon eniyan mejidinlogbon loti ni aisan oun nipinle Eko.

Eniyan meje loti lugbadie lolulu ileyi tise Abuja, eniyan meji loti ko arun na nipinle Ogun, eniyan kan ipinle Oyo ati Ekiti ati Edo.

Ogunkola/Famakin

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *