Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ni fún gbígba oyè àkọ́kọ́ fáwọn tówá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Ìjọba àpapọ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ètò ẹ̀kọ́ni ìmọ̀ oyé àkọ́kọ́ láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n yíká orílẹ̀èdè yí fún àwọn tón singbà tó jẹ́ ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta àti mọ́kàndínládota níye.

Alákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé, ọ̀gbẹ́ni Rauf Aregbẹsọla ló sọ̀rọ̀ yí nílu Abuja lásìkò tón sísọ lójú àwọn ọkọ isẹ́ mọ́kàndín lọ́gọ́ta fún lílò àwọn ọgbà àtúnse.

Gẹ́gẹ́bí ọ̀gbẹ́ni Aregbẹsọla se ní ẹgbẹ̀rún kan àwọn ẹlẹ́wọ̀n yi ni wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ fún ìdánwò àsejáde nílèwé gíga tónbọ̀.

Ó wá gbóríyìn fún bí àwọn òsìsẹ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, fún bí wọ́n se ri dájú pé, wọ́n se  àmúlò tó yẹ láti ripé àrùn Covid-19 kò tànkélẹ̀ pẹ̀lú àtọ́kasí pé ìjọba ti gbé ìgbésẹ̀ láti mú àdínkù bá iye àwọn tó wà nínú ọgbà àtúnse yíká ilẹ̀yí tíwọ́n sì ti yọ̀nda àwọn tó fẹ̀ wọ ẹgbẹ̀rún mẹ̀rin níye.

Ọlọlade Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *