Onímọ̀ nípa òsèlú kan, ọ̀gbẹ́ni Dọlapọ Ogunsọla ti sàpèjúwe, rògbòdìyàn tón wáyé nínú ẹgbẹ́ òsèlú,APC, nípinlẹ̀ Ẹdo gẹ́gẹ́bí èyí tí kò ní nípa rere fún ẹgbẹ́ náà pẹ̀lú ìbò sípò Gómìnà tí wọ́n ńgbaradì fún.

Ó sọ̀rọ̀ yí lásìkò tón bá akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria sọ̀rọ̀, lórí bí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn se si fòfin de nini kí Adams Oshiomhole alága ẹgbẹ́ ọ̀hún lọ fìdí mọ́lé náà, fún gbà díẹ̀.

Ọgbẹ́ni Ogunsọla fi àidùnú rẹ̀ hàn lórí ìgbésẹ̀ yi tó sì sọ pé osese kí Gómìnà tó wà lórí ipò Ọbasẹki lọ sínú ẹgbẹ́ miràn èyí tí yo jẹ́ kálàfo ńlá wà nínú ẹgbẹ́ APC, nípinlẹ̀ Ẹdo.

Ótọ́kasi pé, kò sí ẹgbẹ́ tí Gómìnà lè lóun darapọ̀ mọ́, tí wọn kò ní tètè gba wọlé.

Onímọ̀ nípa òsèlú náà, sọ pé yíyọ Oshiomọlẹ gẹ́gẹ́bí alága ni yo fa rògbòdìyàn nínú ẹgbẹ́ ọ̀hún.

Lána ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sì fi òntẹ̀ lu yíyọ Adams Oshiọmọle tí kò sì ju wákàtí mélo kan lọ tí Gómìnà kéde pé òun ti kúrò nínú ẹgbẹ́ ọ̀hún.

Afọnja Ọlọlade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *