Yoruba

Obinrin Miiran Tun Ti Padanu Emi Re N’ijoba Akinyele

Obinrin tojo ori re was laarin ogun odun ni won tun ti sa lada laarin ori ni kutukutu owuro yi lati oowo awon ti won funra si pe won je apani setutu ni agbegbe oja sasa nilu ibadan.

Iroyin ni obinrin ohun ti won o ti mo oruko re ni o fo abo niwaju ile re lasiko ti eni ti o sa lada ohun sise ibi naa to si fi sile sinu agbara eje.

Eniti oro naa soju re ti ko fe so oruko ara re ni oko obinrin ti won sapa naa ni oun nbo lati mosalasi nigbati o ba oku iyawo re nile ko to ke gbajare si awon alamulegbe re.

Awon olopa ni won ti gbe oku obinrin naa lo si ile iwosan ti enikeni o mo. Nibayi awon olopa ni awon ti ndode awon to huwa laabi ohun.

A o mu wa si iranti wipe o ti le ni awon merin ti won ti seku pa ni laarin ose die seyin ni ijoba ibile akinyele.

 Lekan Olayiwola/Yemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *