Yoruba

Banki Agbaye Nawo Iranwo Si Eka Ina Oba Lorile Ede Naijiria

Banki agbaye ti buwolu owoya oni millionu eedegberin o le ni aadota, 750 million dollars ti egbe to wa fun idagbasoke lagbaye fun agbedide eka ina oba nile Naijiria.

Ninu atejade ti banki naa fi sita nilu Abuja, o ni igbese naa ni won gbe lati lee ri pe eka ina oba tubo fese rinle ki won si lee ko akoyawo.

Atejade naa salaye wipe ida metadinlaadota awon omo ile yi ni won ni anfani si ina oba nigbati awon ti won nni nkoju idakuruku ina oba.

O fikun wipe, sisatunse si eka ina oba ni paapajulo fun awon eka to npese nkan nile yi se pataki lati muki oro aje tubo gbooro sii leyin ajakale arun Covid-19.

Yemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *