Ìjọba àpapọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sìni pín fọ́rmu ìgbanisísẹ́ pàtàkì fún àwọn èyàn ẹgbẹ̀rún kan nìjọba ìbílẹ̀ kọ̀kan yíká orílẹ̀èdè yí tẹ̀ka tìpínlẹ̀ ọ̀ya.

Alága ìgbìmọ̀ tón mójútó gbígbanisísẹ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ ọ̀gbẹ́ni Ọpẹ Salami ló jẹ́ kọ́rọ̀ yi di mímọ̀ lasìkò tón bá akọ̀ròyìn ilésẹ́ Premier F.M sọ̀rọ̀.

Ọgbẹni Salami ẹni tó sọpé fọ́rmu náà ti wà yíká gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, sọ pé wọ́n kòní sanwó kankan fi gba fọ́rmu náà, ó sàlàyé pé òní àti ọ̀la nìkan ni ówà fun ètò ọ̀hún.

Ọgbẹni Salami sọ̀rọ̀ ìdánilójú pé, àbò ẹ̀mí àti dúkia tó péye ló ti wà n kalẹ̀ láwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo láti lè dènà ìsẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn.

Alága wá rọ gbogbo èyàn àwùjọ tí wọ́n bá nífẹ sí isẹ́ pàtàkì ọ̀hún láti firawọnji, kí wọ́n sì ri dájú pé wọ́n kọ́ number ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ wọn sórí ibi tó yẹ.

Ololade Afọnja   

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *