Yoruba

Ikọ̀ amúsẹ́yá ìjọba àpapọ̀ farun covid-19, sàfikún ìlànà atẹlefún ìgbérọsọ àwọn pápákọ̀ òfirifú.

Ikọ̀ amúsẹ́ yáà, ìjọba àpapọ̀ fárùn covid-19 PTF ti sèkìlọ̀ fáwọn èèyàn tó ńwọlé  sórílẹ̀èdè yíì, láti tẹ̀lé àwọn ìlànà tóóyẹ bí àwọn páapáakọ̀ òfurufú se bẹ̀rẹ̀ isẹ́ padà.

Olùdarí àjọ PTF, Dókítà Sani Aliyu, ẹnitó sọ̀rọ̀ yíì, níbi àbọ̀ isẹ́ ikọ̀ náà nílu Abuja sọpé, gbogbo àwọn arìnrìn-àjò tó ńwọlé sílẹ̀ yíì, nílò ìwé-ẹ̀rí àyẹ̀wò àrùn covid-19 tósì gbọ́dọ̀ wáyé yálà wákàtí méjìléládọrun tàbí ọjọ́ méje sáàjú ọjọ́ ìrìnàjò.

Ótún sàlàyé pé, àwọn arìnrìn-àjò tóbáfẹ́ wọlé sílẹ̀ Nàijírìa, gbọ́dọ̀ forúkọ sílẹ̀ lójú òpó ilẹ̀ Nàigjírìa kíwọ́n si sanwó fún àyẹ́wò tí yóò wáyé nílẹ̀ yíì, kíwọ́n sì dáhùn àwọn ìbere tóníse pẹ̀lú ètò ìlera lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Ó sọdi mímọ̀ pé, níbamu pẹ̀lú gbígbaradì fún ìbẹ̀rẹ̀ isẹ́ padpa àwọn páapáakọ̀ òfurufú, lọ́jọ́ karun osù yíì.

Ẹwẹ ikọ̀ amúsẹ́yá ọ̀hún tí ńsisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ láti fẹsẹ̀ òfin tóòyẹ múlẹ̀ nídi àbò àwọn arìnrìn-àjò dídènà kíkóò àrùn mi wọ orílẹ̀èdè yíì tófimọ́ dídènà ìtànkálẹ̀ àarùn covid-19.

idogbe    

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *