News Yoruba

Agbebon Gbemi Enikan Nipinle Ekiti.

Kowe ke ko ha nilu Ado Ekiti nigbati awon agbebon gbemi Ogan kan nile ise to nrisi oro Ijoba Ibile nipinle Ekiti, Ogbeni David Jejelowo.

Akoroyin ile ise Radio Nigeria rii gbo wipe won gbemi okunrin naa ni kutukutu owuro oni nile re to wa ni Igirigiri nilu Ado Ekiti.

Ohun ti won ko tii lee fiidi re mule ni bi won se paa ati idi ti won fi demi re legbodo ti isele yi si ti mu ki awon eniyan agbegbe naa wa ninu iberu bojo.

Alukoro ile ise Olopa Nipinle naa, Ogbeni Sunday Abutu fidi isele ohun mule nigbati won kan sii, o wa ni iwadi ti bere lori isele naa.

O seleri lati tubo soro lori isele naa fun awon oniroyin nigbati a ba ya loni.

Babatuyi/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *