News Yoruba

Ijoba Ipinle Ekiti Kede Iwole Akeko

Gomina Ipinle Ekiti, Omowe Kayode Fayemi ti kede sisi ile iwe fun awon akeko ni ipele eko keji nile-eko-Girama-agba SS2 ipele eko keta nile eko Girama kekere JSS3 ati awon oniwe mefa alakobere bere lati ojo kokanlegun osu yi.

Bakanna awon akeke nipele eko-Girama kekere keji, JSS2 ati ikarun pry 4 ati 5 ni won yio wole ni ojo kejidinlogbon osu yi nigbati awon yoku yio wole ni ojo kokandinlogun osun to nbo.

Gomina Fayemi ninu oro to baa won eniyan ipinle naa so lori ibiti nkan de duro lori arun Covid 19 ni awon akeko kekeke ti a mo ni Sursery and Kindergarten ni won yio wole lojo keji osu kejila odun yi.

O ni awon iel eko giga nipinle naa le bere si ni silekun won bere lati ojo keji osu to n bo lo, leyi ti o ni yio da lori bi won ti se gbaradi, ti won si se tele awon liana ti won la kale to.

Gomina wa gba awon alase ile-eko giga lamonran lati jumo sise po pelu igbimo amuseya lori Covid 19 nipinle Ekiti lori itosona ati awon ohun ti oye ki won si ki won to silekun pada.

Ogunrinde/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *