Yoruba

Ijoba Se Kilo Fawon Ileepo Lori Tita Epo Pe Faraalu

Ileese Ijoba apapo to wa fun karakata ati idokowo ti soo di mimo pe won o ni kaare ninu igbiyanju ati rii daju pea won ileepo n ta epo pe perepere faraalu.

Alamojuto eka to n ri si odiwon nile naa, eka tipinle Oyo Alhaji Shuaib Hambali lo si paya oro yi lasiko ti akoroyin Radio Nigeria n foro was lenuwo nilu Ibadan.

Alhaji Hambali, eni to koro oju si bi awon omo ile yi se maa n se atotonu pe opo illepo ni odiwon won ko peye salaye wipe ileese naa ko kaare lati ri daju pea won araalu n ra epo to pe iye owo ti won san.

O tenumo pe won ti paa lase fun gbogbo ileepo pe ki won rii daju pe ero ti won fi nta epo pe geerege.

Oludari eka to n ri si odiwon, Alhaji Abubakar Dangaladina salaye wipe eka naa ko ni faaye gba ileepo Kankan lati maa se magomago pelu ero ti won fi n ta epo.

Babatunde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *