News Yoruba

Àwọn Èèkàn Àwùjọ Kẹ́dùn Ìpapòdà Bọ́bajírò Tìlú ’Bàdàn.

Àwọn èkàn nílẹ̀ yí ti bẹ̀rẹ̀ siní fi èrò wọn hàn lórí ìpapòdà akọ̀wé tẹ́lẹ̀rí fún ìjọna ológun lẹ́kùn ìwọ̀ orun àtijọ́ nílẹ̀ Nàijírìa, olóòyè Theophilus Akinyẹle.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, akọ̀wé tẹ́lẹ̀rí fún ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, olóòyè Bisi Adesọla sàpèjúwe olóògbe Akinyẹle gẹ́gẹ́bí akínkajú ẹ̀dá, tójẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́.

Óní ipa rere tó là kalẹ̀, papa jija fún ètò ọmọnìyàn àti fifi ẹsẹ òdodo múlẹ̀ ní wọ́n kọn ni gbàgbé láilái.

Nígbà tón bú ẹnu àtẹlu, bí ìwà ọmọlúàbí se ti dẹnu kọlẹ̀ lárin àwọn èyàn àwùjọ, olóòyè Adesọla rọ àwọn èyàn ilẹ̀ yí láti wo àwòkọ́se rere lára ológbe Theophilus Akinyẹle.

Olóòyè Theophilus Akinyẹle, ẹni tó jáde láyé lána lẹ́ni ọdún méjì dín ládọrun, ló ti fi ìgbàkan rí jẹ́ gíwá ilé ẹ̀kọ́ gíga versity ilé-ifẹ̀, èyí tí wọ́n ńpè ni ilé ẹ̀kọ́ gíga versity Ọbafẹmi Awolọwọ báyi, bákanà ló túnjẹ́ olùdámọ́ran pàtàkì sí Àarẹ tẹ́lẹ̀rí Sheu Shagari.

Olóòyè Theophilus Akinyẹle ní se bọ́bajíròrò tilẹ̀ bàdàn kótó dipé ó papòdà.

Bákanà, Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onómọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde, ti sàpèjúwe ìpapòdà bọ́bajíròrò tílù bàdà tótúnjẹ́ akọ̀wé àgbà tẹ́lẹ̀rí fún ìjọba ológun, olóòyè Theophilus Akinyẹle gẹ́gẹ́bí àdánù ńlá sípinlẹ̀ yi.

 Gómìnà sọ̀rọ̀ yí dimímọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fọwọ́sí tó sì se lálàyé pé ìpapòdà P.A Akinyẹle túnmọ̀sí pé òunti pàdánù bàbá tó se fẹ̀yìntì.

 Gómìnà Makinde tọ́kasi pé olóògbe Theophilus Akinyẹle, ni eledua jínki pẹ̀lú ìmọ̀ tó péye, tó sì tún ní ìrírí, bákanà ni ifẹ tó ní si ọmọnìyàn kó se sàkàwé.

Famakin/Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *