Adájọ́ àgbà ilẹ̀ yí, onídajọ́ Tanko Muhammad ti rọ àwọn onídajọ́ jákèjádò ilẹ̀ yí láti máà gbọ́ ẹjọ́ tó wà níwájú wọn lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Adájọ́ àgbà ẹnití ó sọ̀rọ̀ yí níbi ayẹyẹ ètò ìgbaniwọ́lé síbi ètò ìdánilẹ́kọ fún àwọn adájọ́ tuntun tí ilé ẹ̀kọ́ nípa ìgbẹ́jọ́ ilẹ̀ yí èyítí ó wáyé lórí ẹ̀rọ ayélujára tẹnumọ wípé bí wọ́n bá ńgbọ́ ẹjọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ ríì dájú wípé wan tẹ̀lé ounti òfin sọ.

Ó ní àyàkalẹ̀ àrùn covid-19 ló ti sọ ọ̀pọ̀ ǹkan di akúrẹtẹ̀ láiyọ bí ìgbẹ́jọ́ se falẹ̀ sílẹ̀.

Onídajọ́ Muhammad tún rọ àwọn adájọ́ náà láti se isẹ́ wọn bíì isẹ́ kí wọ́n sì yàgò fún gbigba owo tòtọ́.

Ó fikun wípé àwọn adájọ́ tuntun ọ̀ún gbọ́dọ̀ lóye àyíká tí wọ́n ti ńsisẹ́ dáàda láti léè yágò fún àwọn ìpèníjà àti àwọn ohun tó léè bì wọ́n subú nígbàtí wọ́n bá ńgbọ́ ẹjọ́ tí wọ́n bá gbé wá síwájú wọn.

Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *